Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 19:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. PẸLUPẸLU iwọ pohùn-rére ẹkun fun awọn ọmọ-alade Israeli,

2. Si wipe, Kini iyá rẹ? Abo kiniun: o dubulẹ lãrin kiniun, o bọ́ awọn ọmọ rẹ lãrin ọmọ kiniun.

3. O si tọ́ ọkan ninu ọmọ rẹ̀ dàgba: o di ọmọ kiniun, o si kọ́ ati ṣọdẹ; o pa enia jẹ.

4. Awọn orilẹ-ède pẹlu gburo rẹ̀: a mu u ninu iho wọn, nwọn si fi ẹ̀wọn mu u lọ si ilẹ Egipti.

5. Nigbati o si ri pe on si duro, ti ireti rẹ̀ si sọnu, nigbana ni o mu omiran ninu ọmọ rẹ̀, o si sọ ọ di ọmọ kiniun.

6. On si lọ soke lọ sodo lãrin awọn kiniun, o di ọmọ kiniun, o si kọ́ lati ṣọdẹ, o si pa enia jẹ.

7. On si mọ̀ awọn opo wọn, o si sọ ilu-nla wọn di ahoro; ilẹ na di ahoro, ati ẹkún rẹ̀, pẹlu nipa ariwo kike ramuramu rẹ̀.

8. Nigbana ni awọn orilẹ-ède kó tì i nihà gbogbo lati ìgberiko wá, nwọn si na awọ̀n wọn le e lori: a mu u ninu iho wọn.

9. Nwọn si fi i sinu ẹṣọ́ ninu ẹ̀wọn, nwọn si mu u wá sọdọ ọba Babiloni: nwọn mu u lọ sinu ilu olodi, ki a má ba gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ lori oke Israeli.

10. Iyá rẹ dabi àjara kan ninu ẹjẹ rẹ, ti a gbìn si eti odò, on kún fun eso, o si kún fun ẹka nitori ọ̀pọlọpọ odò.

Ka pipe ipin Esek 19