orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 15 Yorùbá Bibeli (YCE)

Òwe Nípa Igi Àjàrà

1. Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

2. Ọmọ enia, kini igi ajara fi ju igikigi lọ, tabi ju ẹka ti o wà lãrin igi igbo?

3. A ha le mu igi lara rẹ̀ ṣe iṣẹkiṣẹ? tabi enia le mu ẽkàn lara rẹ̀ lati fi ohunkohun kọ́ sori rẹ̀.

4. Kiyesi i, a jù u sinu iná bi igi, iná si jo ipẹkun rẹ̀ mejeji, ãrin rẹ̀ si jona. O ha yẹ fun iṣẹkiṣẹ bi?

5. Kiyesi i, nigbati o wà li odidi, kò yẹ fun iṣẹ kan: melomelo ni kì yio si yẹ fun iṣẹkiṣẹ, nigbati iná ba ti jo o, ti o si jona?

6. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Bi igi ajara lãrin igi igbó, ti mo ti fi fun iná bi igi, bẹ̃ni emi o fi ara Jerusalemu ṣe.

7. Emi o si doju mi kọ wọn, nwọn o jade kuro ninu iná kan, iná miran yio si jo wọn, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati mo ba dojukọ wọn.

8. Emi o si sọ ilẹ na di ahoro, nitori ti nwọn ti dẹṣẹ, ni Oluwa Ọlọrun wi.