Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 18:8-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ẹniti kò fi fun ni lati gba ẹdá, bẹ̃ni kò gba elékele, ti o ti fa ọwọ́ rẹ̀ kuro ninu aiṣedẽde, ti o ti mu idajọ otitọ ṣẹ lãrin ọkunrin ati ọkunrin,

9. Ti o ti rìn ninu aṣẹ mi, ti o si ti pa idajọ mi mọ, lati hùwa titọ́; on ṣe olõtọ, yiyè ni yio yè, ni Oluwa Ọlọrun wi.

10. Bi o ba bi ọmọkunrin kan ti iṣe ọlọṣà, oluta ẹ̀jẹ silẹ, ti o si nṣe ohun ti o jọ ọkan ninu nkan wọnyi si arakunrin rẹ̀.

11. Ti kò si ṣe ọkan ninu gbogbo iṣẹ wọnni, ṣugbọn ti o tilẹ ti jẹun lori oke, ti o si ba obinrin aladugbo rẹ̀ jẹ,

12. Ti o ti ni talaka ati alaini lara; ti o ti fi agbara koni, ti kò mu ohun ògo pada, ti o ti gbe oju rẹ̀ soke si oriṣa, ti o ti ṣe ohun irira,

13. Ti o ti fi fun ni lati gba ẹdá, ti o si ti gba èle: on o ha yè bẹ̃? on ki yio yè: on ti ṣe gbogbo ohun irira wọnyi; kikú ni yio kú: ẹjẹ rẹ̀ yio wà lori rẹ̀.

14. Si kiye si i, bi o ba bi ọmọkunrin ti o ri gbogbo ẹ̀ṣẹ baba rẹ̀ ti o ti ṣe, ti o si bẹ̀ru, ti kò si ṣe iru rẹ̀,

15. Ti kò si jẹun lori oke, ti kò gbe oju rẹ̀ soke si oriṣa ile Israeli, ti kò ba obinrin aladugbo rẹ̀ jẹ,

16. Ti kò ni ẹnikan lara, ti kò dá ohun ògo duro, ti kò fi agbara koni, ṣugbọn ti o ti fi onjẹ rẹ̀ fun ẹniti ebi npa, ti o si ti fi ẹ̀wu bo ẹni-ihoho,

17. Ti o ti mu ọwọ́ rẹ̀ kuro lara ẹni-inilara, ti kò ti gba ẹdá tabi elé ti o ti mu idajọ mi ṣẹ, ti o ti rìn ninu aṣẹ mi; on kì yio kú nitori aiṣedẽde baba rẹ̀, yiyè ni yio yè.

18. Bi o ṣe ti baba rẹ̀, nitoripe o fi ikà ninilara, ti o fi agbara ko arakunrin rẹ̀; ti o ṣe eyiti kò dara lãrin enia rẹ̀, kiye si i, on o tilẹ kú ninu aiṣedẽde rẹ̀.

19. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ẽṣe? ọmọ kò ha ru aiṣedẽde baba? Nigbati ọmọ ti ṣe eyiti o tọ́ ati eyiti o yẹ, ti o si ti pa gbogbo aṣẹ mi mọ, ti o si ti ṣe wọn, yiyè ni yio yè.

Ka pipe ipin Esek 18