Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 18:25-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Ṣugbọn ẹnyin wipe, ọ̀na Oluwa kò gún. Gbọ́ nisisiyi, iwọ ile Israeli; ọ̀na mi kò ha gún? ọ̀na ti nyin kọ́ kò gún?

26. Nigbati olododo kan ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀, ti o si huwà aiṣedẽde, ti o si kú ninu wọn; nitori aiṣedẽde rẹ̀ ti o ti ṣe ni yio kú.

27. Ẹwẹ, nigbati enia buburu ba yipada kuro ninu ìwa buburu rẹ̀ ti o ti ṣe, ti o si ṣe eyiti o tọ́, ati eyiti o yẹ, on o gba ọkàn rẹ̀ là lãye.

28. Nitoripe o bẹ̀ru o si yipada kuro ninu gbogbo irekọja rẹ̀ ti o ti ṣe, yiyè ni yio yè, on kì yio kú.

29. Ṣugbọn ile Israeli wipe, Ọ̀na Oluwa kò gún. Ile Israeli, ọ̀na mi kò ha gún? ọ̀na ti nyin kọ́ kò gún?

30. Nitorina emi o dá nyin lẹjọ, ile Israeli, olukuluku gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ni Oluwa Ọlọrun wi. Ẹ yipada, ki ẹ si yi kuro ninu gbogbo irekọja nyin; bẹ̃ni aiṣedẽde kì yio jẹ iparun nyin.

31. Ẹ ta gbogbo irekọja nyin nù kuro lọdọ nyin, nipa eyiti ẹnyin fi rekọja; ẹ si dá ọkàn titun ati ẹmi titun fun ara nyin: nitori kini ẹnyin o ṣe kú, ile Israeli?

32. Nitoripe emi kò ni inu didùn si ikú ẹniti o kú, ni Oluwa Ọlọrun wi: nitorina ẹ yi ara nyin pada, ki ẹ si yè.

Ka pipe ipin Esek 18