Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 18:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,

2. Kini ẹnyin rò ti ẹnyin fi npowe yi niti ilẹ Israeli, pe, Awọn baba ti jẹ eso àjara kíkan, ehin awọn ọmọ si kan.

3. Oluwa Ọlọrun wipe, bi mo ti wà, ẹnyin kì yio ri àye lati powe yi mọ ni ilẹ Israeli.

4. Kiye si i, gbogbo ọkàn ni t'emi; gẹgẹ bi ọkàn baba ti jẹ t'emi, bẹ̃ni t'emi ni ọkàn ọmọ pẹlu; ọkàn ti o bá ṣẹ̀, on o kú.

5. Ṣugbọn bi enia kan ba ṣe olõtọ, ti o si ṣe eyiti o tọ ati eyiti o yẹ,

6. Ti kò si jẹun lori oke, ti kò si gbe oju rẹ̀ soke si awọn oriṣa ile Israeli, ti kò si bà obinrin aladugbo rẹ̀ jẹ, ti kò sì sunmọ obinrin ti o wà ninu aimọ́ rẹ̀.

7. Ti kò si ni ẹnikan lara, ṣugbọn ti o ti fi ohun ògo onigbèse fun u, ti kò fi agbara kó ẹnikẹni, ti o ti fi onjẹ rẹ̀ fun ẹniti ebi npa, ti o si ti fi ẹwu bo ẹni-ihoho.

8. Ẹniti kò fi fun ni lati gba ẹdá, bẹ̃ni kò gba elékele, ti o ti fa ọwọ́ rẹ̀ kuro ninu aiṣedẽde, ti o ti mu idajọ otitọ ṣẹ lãrin ọkunrin ati ọkunrin,

Ka pipe ipin Esek 18