1. Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
2. Ọmọ enia, pa alọ́ kan, si pa owe kan fun ile Israeli;
3. Si wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Idì nla kan, pẹlu apá nla, alapá gigùn, o kún fun iyẹ́; ti o ni àwọ alaràbarà wá si Lebanoni, o si mu ẹka igi Kedari ti o ga julọ.
4. O ke ori ọ̀munú ẹka rẹ̀ kuro, o si mu u lọ si ilẹ òwo kan; o gbe e kalẹ ni ilu awọn oniṣòwo.
5. O mu ninu irugbìn ilẹ na pẹlu, o si gbìn i sinu oko daradara kan; o fi si ibi omi nla, o si gbe e kalẹ bi igi willo.
6. O si dagba, o si di igi àjara ti o bò ti o kuru, ẹka ẹniti o tẹ̀ sọdọ rẹ̀, gbòngbo rẹ̀ si wà labẹ rẹ̀; bẹ̃ni o di ajara, o si pa ẹka, o si yọ ọ̀munú jade.