Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 16:61-63 Yorùbá Bibeli (YCE)

61. Iwọ o si ranti ọ̀na rẹ, oju o si tì ọ, nigbati iwọ ba gba awọn arabinrin rẹ, ẹgbọ́n rẹ ati aburò rẹ: emi o si fi wọn fun ọ bi ọmọbinrin, ṣugbọn ki iṣe nipa majẹmu rẹ.

62. Emi o si gbe majẹmu mi kalẹ pẹlu rẹ; iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

63. Ki iwọ ki o le ranti, ki o si le dãmu, ki iwọ ki o má si le yà ẹnu rẹ mọ nitori itiju rẹ, nigbati inu mi ba tutù si ọ, nitori ohun ti iwọ ti ṣe, ni Oluwa Ọlọrun wi.

Ka pipe ipin Esek 16