Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 16:44-48 Yorùbá Bibeli (YCE)

44. Kiyesi i, olukuluku ẹniti npowe ni yio powe yi si ọ, wipe, Bi iyá ti ri, bẹ̃ni ọmọ rẹ̀ obinrin.

45. Iwọ ni ọmọ iyá rẹ ti o kọ̀ ọkọ rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀; iwọ ni arabinrin awọn arabinrin rẹ, ti o kọ̀ awọn ọkọ wọn ati awọn ọmọ wọn: ará Hiti ni iyá rẹ, ará Amori si ni baba rẹ.

46. Ẹgbọn rẹ obinrin si ni Samaria, on ati awọn ọmọbinrin rẹ ti ngbe ọwọ́ osì rẹ: ati aburo rẹ obinrin ti ngbe ọwọ́ ọ̀tun rẹ ni Sodomu ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin.

47. Ṣugbọn iwọ kò rin ni ọ̀na wọn, iwọ kò si ṣe gẹgẹ bi irira wọn: ṣugbọn, bi ẹnipe ohun kekere ni eyini, iwọ bajẹ jù wọn lọ ni gbogbo ọ̀na rẹ.

48. Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, Sodomu arabinrin rẹ, on, tabi awọn ọmọ rẹ̀ obinrin kò ṣe gẹgẹ bi iwọ ti ṣe, iwọ ati awọn ọmọ rẹ obinrin.

Ka pipe ipin Esek 16