Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 16:19-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Onjẹ mi pẹlu ti mo ti fun ọ, iyẹfun daradara, ati ororo, ati oyin, ti mo fi bọ́ ọ, iwọ tilẹ gbe e kalẹ niwaju wọn fun õrùn didùn: bayi li o si ri, ni Oluwa Ọlọrun wi.

20. Pẹlupẹlu iwọ ti mu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ obinrin, ti iwọ ti bi fun mi, awọn wọnyi ni iwọ si ti fi rubọ si wọn lati jẹ. Ohun kekere ha ni eyi ninu ìwa panṣaga rẹ,

21. Ti iwọ ti pa awọn ọmọ mi, ti o si fi wọn fun ni lati mu wọn kọja lãrin iná fun wọn?

22. Ati ni gbogbo ohun irira rẹ, ati panṣaga rẹ, iwọ kò ranti ọjọ ewe rẹ, nigbati iwọ wà nihoho ti o si wà goloto, ti a si bà ọ jẹ ninu ẹjẹ rẹ.

23. O si ṣe lẹhin gbogbo ìwa buburu rẹ, (Egbe, egbe ni fun ọ! ni Oluwa Ọlọrun wi;)

24. Ti iwọ si kọ́ ile giga fun ara rẹ, ti iwọ si ṣe ibi giga ni gbogbo ita fun ara rẹ.

25. Iwọ ti kọ́ ibi giga rẹ ni gbogbo ikórita, o si ti sọ ẹwà rẹ di ikorira, o si ti ya ẹsẹ rẹ si gbogbo awọn ti nkọja, o si sọ panṣaga rẹ di pupọ.

26. Iwọ ti ba awọn ara Egipti aladugbo rẹ, ti o sanra ṣe agbere, o si ti sọ panṣaga rẹ di pupọ, lati mu mi binu.

27. Kiye si i, emi si ti nawọ mi le ọ lori, mo si ti bu onjẹ rẹ kù, mo si fi ọ fun ifẹ awọn ti o korira rẹ, awọn ọmọbinrin Filistia, ti ìwa ifẹkufẹ rẹ tì loju.

28. Iwọ ti ba awọn ara Assiria ṣe panṣaga pẹlu, nitori iwọ kò ni itẹlọrun; nitotọ, iwọ ti ba wọn ṣe panṣaga, sibẹsibẹ kò si le tẹ́ ọ lọrùn,

29. Iwọ si ti sọ agbere rẹ di pupọ lati ilẹ Kenaani de Kaldea; sibẹsibẹ eyi kò si tẹ́ ọ lọrun nihinyi.

30. Oluwa Ọlọrun wipe, aiyà rẹ ti ṣe alailera to, ti iwọ nṣe nkan wọnyi, iṣe agídi panṣaga obinrin;

31. Nitipe iwọ kọ́ ile giga rẹ ni gbogbo ikoríta, ti o si ṣe ibi giga rẹ ni gbogbo ita; iwọ kò si wa dabi panṣaga obinrin, nitipe iwọ gan ọ̀ya.

Ka pipe ipin Esek 16