Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 14:8-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Emi o si dojukọ ọkunrin na, emi o si fi i ṣe àmi ati owe, emi o si ké e kuro lãrin awọn enia mi; ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.

9. Bi a ba si tan wolĩ na jẹ nigbati o sọ ohun kan, Emi Oluwa ni mo ti tan wolĩ na jẹ, emi o si nawọ mi le e, emi o si run u kuro lãrin Israeli enia mi.

10. Awọn ni yio si rù ìya aiṣedẽde wọn; ìya wolĩ na yio ri gẹgẹ bi ìya ẹniti o bẽre lọdọ rẹ̀.

11. Ki ile Israeli má ba ṣako lọ kuro lọdọ mi mọ, ki nwọn má ba fi gbogbo irekọja wọn bà ara wọn jẹ mọ, ṣugbọn ki nwọn ki o le jẹ enia mi, ki emi si le jẹ Ọlọrun wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi.

12. Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe,

13. Ọmọ enia, nigbati ilẹ na ba ṣẹ̀ si mi nipa irekọja buburu, nigbana ni emi o nawọ mi le e, emi o si ṣẹ́ ọpa onjẹ inu rẹ̀, emi o si rán ìyan si i, emi o si ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀:

14. Bi awọn ọkunrin mẹta wọnyi, Noa, Danieli, ati Jobu tilẹ wà ninu rẹ̀, kiki ẹmi ara wọn ni nwọn o fi ododo wọn gbàla, li Oluwa Ọlọrun wi.

15. Bi mo ba jẹ ki ẹranko buburu kọja lãrin ilẹ na, ti nwọn si bà a jẹ, tobẹ̃ ti o di ahoro, ti ẹnikan kò le là a ja nitori awọn ẹranko na.

16. Bi awọn ọkunrin mẹta wọnyi tilẹ wà ninu rẹ̀, Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nwọn kì yio gbà ọmọkunrin tabi ọmọbinrin là; awọn nikan li a o gbàla, ṣugbọn ilẹ na yio di ahoro.

17. Tabi bi mo mu idà wá sori ilẹ na, ti mo si wipe, Idà, la ilẹ na ja; tobẹ̃ ti mo ke enia ati ẹranko kuro ninu rẹ̀:

18. Bi awọn ọkunrin mẹta yi tilẹ wà ninu rẹ̀, Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nwọn kì yio gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin là, ṣugbọn awọn tikara wọn nikan li a o gbàla.

Ka pipe ipin Esek 14