Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 13:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe:

2. Ọmọ enia, sọtẹlẹ si awọn woli Israeli ti nsọtẹlẹ, ki o si wi fun awọn ti nti ọkàn ara wọn sọtẹlẹ pe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa;

3. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, egbé ni fun awọn aṣiwere woli, ti nwọn ntẹ̀le ẹmi ara wọn, ti wọn kò si ri nkan!

4. Israeli, awọn woli rẹ dabi kọ̀lọkọ̀lọ ni ijù,

5. Ẹnyin kò ti goke lọ si ibi ti o ya, bẹ̃ni ẹ kò si tun odi mọ fun ile Israeli lati duro li oju ogun li ọjọ Oluwa.

6. Nwọn ti ri asan ati àfọṣẹ eke, pe, Oluwa wi: bẹ̃ni Oluwa kò rán wọn, nwọn si ti jẹ ki awọn ẹlomiran ni ireti pe, nwọn o fi idí ọ̀rọ wọn mulẹ.

7. Ẹnyin kò ti ri iran asan, ẹ kò si ti fọ àfọṣẹ eke, ti ẹnyin wipe, Oluwa wi bẹ̃? bẹ̃ni emi kò sọrọ.

8. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ẹnyin ti sọ̀rọ asan, ẹnyin si ti ri eke, nitorina, kiyesi i, mo dojukọ nyin, ni Oluwa wi.

9. Ọwọ́ mi yio si wà lori awọn woli, ti nwọn ri asan, ti nwọn si nfọ àfọṣẹ eke; nwọn kì yio si ninu ijọ awọn enia mi, bẹ̃ni a kì yio kọwe wọn sinu iwe ile Israeli; bẹ̃ni nwọn kì yio wọ̀ ilẹ Israeli, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

10. Nitori, ani nitori ti nwọn ti tàn awọn enia mi wipe, Alafia; bẹ̃ni kò si alafia, ọkan si mọ ogiri, si kiyesi, awọn miran si nfi amọ̀ ti a kò pò rẹ́ ẹ.

11. Wi fun awọn ti nfi amọ̀ aipò rẹ́ ẹ, pe, yio ṣubu; òjo yio rọ̀ pupọ; ati Ẹnyin, yinyín nla, o si bọ́; ẹfũfu lile yio si ya a.

Ka pipe ipin Esek 13