Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 11:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẸMI si gbe mi soke, o si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na ile Oluwa ti ilà õrun ti o kọju siha ilà-õrùn, si kiyesi i, ọkunrin mẹdọgbọn wà nibi ilẹkun ẹnu-ọ̀na; ninu awọn ẹniti mo ri Jaasania ọmọ Assuri, ati Pelatia ọmọ Benaia, awọn ijoyè awọn enia.

2. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, awọn ọkunrin ti npete ikà ni wọnyi, ti nsi gbimọ̀ buburu ni ilu yi:

3. Awọn ti o wipe, Kò sunmọ tosi; ẹ jẹ ki a kọ ile: ilu yi ni ìgba, awa si ni ẹran.

4. Nitorina sọtẹlẹ si wọn, Ọmọ enia, sọtẹlẹ.

5. Ẹmi Oluwa si bà le mi, o si wi fun mi pe, Sọ̀rọ; Bayi li Oluwa wi; Bayi li ẹnyin ti wi, Ile Israeli, nitoriti mo mọ̀ olukuluku ohun ti o wá si inu nyin.

Ka pipe ipin Esek 11