Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 10:14-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Olukuluku wọn si ni oju mẹrin, oju ekini oju kerubu, oju keji, oju enia, ati ẹkẹta oju kiniun, ati ẹkẹrin oju idi.

15. A si gbe awọn kerubu soke, eyi ni ẹda alãye ti mo ri lẹba odò Kebari.

16. Nigbati awọn kerubu si lọ, awọn kẹkẹ lọ li ẹgbẹ́ wọn: nigbati awọn kerubu si gbe iyẹ́ wọn soke lati fò soke kuro lori ilẹ, kẹkẹ́ kanna kò yipada kuro li ẹgbẹ́ wọn.

17. Nigbati nwọn duro, wọnyi duro; nigbati a si gbe wọn soke, wọnyi gbe ara wọn soke pẹlu; nitori ẹmi ẹda alãye na mbẹ ninu wọn.

18. Ogo Oluwa si lọ kuro ni iloro ile na, o si duro lori awọn kerubu.

19. Awọn kerubu si gbe iyẹ́ wọn soke, nwọn si fò kuro lori ilẹ li oju mi: nigbati nwọn jade lọ, awọn kẹkẹ wà li ẹgbẹ̀ wọn pẹlu, olukuluku si duro nibi ilẹkun ẹnu-ọ̀na ilà-õrun ile Oluwa: ogo Ọlọrun Israeli si wà lori wọn loke.

20. Eyi ni ẹda alãye ti mo ri labẹ Ọlọrun Israeli li ẹba odò Kebari, mo si mọ̀ pe kerubu ni nwọn.

21. Olukuluku wọn ni oju mẹrin li ọkankan, olukuluku wọn si ni iyẹ́ mẹrin; ati aworan ọwọ́ enia wà li abẹ iyẹ́ wọn.

22. Aworan oju wọn si jẹ oju kanna ti mo ri lẹba odò Kebari, iri wọn ati awọn tikara wọn: olukuluku wọn lọ li ọkankan ganran.

Ka pipe ipin Esek 10