Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 1:12-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Olukuluku wọn si lọ li ọkankan ganran: nibiti ẹmi ibá lọ, nwọn lọ; nwọn kò si yipada nigbati nwọn lọ.

13. Niti aworan awọn ẹda alãye na, irí wọn dabi ẹṣẹ́ iná, ati bi irí inà fitila: o lọ soke ati sodo, lãrin awọn ẹda alãye na, iná na si mọlẹ, manamana si jade lati inu iná na wá.

14. Awọn ẹda alãye na si sure, awọn si pada bi kíkọ manamana.

15. Bi mo si ti wo awọn ẹda alãye na, kiyesi i, kẹkẹ́ kan wà lori ilẹ aiye lẹba awọn ẹda alãye na, pẹlu oju rẹ̀ mẹrin.

16. Irí awọn kẹkẹ́ na ati iṣẹ wọn dabi awọ̀ berili: awọn mẹrẹrin ni aworan kanna; irí wọn ati iṣẹ wọn dabi ẹnipe kẹkẹ́ li ãrin kẹkẹ́.

17. Nigbati nwọn lọ, nwọn fi iha wọn mẹrẹrin lọ, nwọn kò si yipada nigbati nwọn lọ.

18. Niti oruka wọn, nwọn ga tobẹ̃ ti nwọn fi ba ni li ẹ̀ru; oruka wọn si kún fun oju yi awọn mẹrẹrin ka.

19. Nigbati awọn ẹda alãye na lọ, awọn kẹkẹ́ lọ li ẹgbẹ́ wọn: nigbati a si gbe awọn ẹda alãye na soke, kuro lori ilẹ, a gbe awọn kẹkẹ́ na soke pẹlu.

20. Nibikibi ti ẹmi ni iba lọ, nwọn lọ; nibẹ li ẹmi fẹ ilọ: a si gbe awọn kẹkẹ́ na soke pẹlu wọn; nitori ẹmi ìye wà ninu awọn kẹkẹ́ na.

21. Nigbati wọnni lọ, wọnyi lọ; nigbati a gbe wọnni duro, wọnyi duro; ati nigbati a gbe wọnni soke kuro lori ilẹ a gbe kẹkẹ́ soke pẹlu wọn: nitori ẹmi ìye wà ninu awọn kẹkẹ́ na.

22. Aworan ofurufu li ori ẹda alãye na dabi àwọ kristali ti o ba ni li ẹ̀ru, ti o nà sori wọn loke.

23. Iyẹ́ wọn si tọ́ labẹ ofurufu, ekini si ekeji: olukuluku ni meji, ti o bo ihà ihín, olukuluku si ni meji ti o bo iha ọhún ara wọn.

24. Nigbati nwọn si lọ, mo gbọ́ ariwo iyẹ́ wọn, bi ariwo omi pupọ, bi ohùn Olodumare, ohùn ọ̀rọ bi ariwo ogun: nigbati nwọn duro, nwọn rẹ̀ iyẹ́ wọn silẹ.

25. Ohùn kan ti inu ofurufu ti o wà lori wọn wá, nigbati nwọn duro, ti nwọn si ti rẹ̀ iyẹ́ wọn silẹ.

26. Ati lori ofurufu ti o wà lori wọn, aworan itẹ kan wà, bi irí okuta safire: ati loke aworan itẹ na li aworan kan bi ori enia wà.

27. Mo si ri bi awọ amberi, bi irí iná yika ninu rẹ̀, lati irí ẹgbẹ́ rẹ̀ de oke, ati lati irí ẹgbẹ́ rẹ̀ de isalẹ, mo ri bi ẹnipe irí iná, o si ni didan yika.

28. Bi irí oṣumare ti o wà ninu awọsanma ni ọjọ ojo, bẹ̃ni irí didan na yika. Eyi ni aworan ogo Oluwa. Nigbati mo si ri, mo dojubolẹ, mo si gbọ́ ohùn ẹnikan ti nsọ̀rọ.

Ka pipe ipin Esek 1