Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 8:5-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. OLUWA si sọ fun Mose pe, Wi fun Aaroni pe, Nà ọwọ́ rẹ pẹlu ọpá rẹ sori odò wọnni, sori omi ṣiṣàn, ati sori ikojọpọ̀ omi, ki o si mú ọpọlọ jade wá sori ilẹ Egipti.

6. Aaroni si nà ọwọ́ rẹ̀ sori omi Egipti; awọn ọpọlọ si goke wá, nwọn si bò ilẹ Egipti.

7. Awọn alalupayida si fi idán wọn ṣe bẹ̃, nwọn si mú ọpọlọ jade wá sori ilẹ Egipti.

8. Nigbana ni Farao pè Mose ati Aaroni, o si wipe, Ẹ bẹ̀ OLUWA, ki o le mú awọn ọpọlọ kuro lọdọ mi, ati kuro lọdọ awọn enia mi; emi o si jẹ ki awọn enia na ki o lọ, ki nwọn ki o le ṣẹbọ si OLUWA.

9. Mose si wi fun Farao pe, Paṣẹ fun mi: nigbawo li emi o bẹ̀bẹ fun ọ, ati fun awọn iranṣẹ rẹ, ati fun awọn enia rẹ, lati run awọn ọpọlọ kuro lọdọ rẹ, ati kuro ninu ile rẹ, ki nwọn ki o kù ni kìki odò nikan?

10. On si wipe, Li ọla. O si wipe, Ki o ri bi ọ̀rọ rẹ; ki iwọ ki o le mọ̀ pe, kò sí ẹniti o dabi OLUWA Ọlọrun wa.

11. Awọn ọpọlọ yio si lọ kuro lọdọ rẹ, ati kuro ninu ile rẹ, ati kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ, ati kuro lọdọ awọn enia rẹ; ni kìki odò ni nwọn o kù si.

12. Mose ati Aaroni si jade kuro lọdọ Farao: Mose si kigbe si OLUWA nitori ọpọlọ ti o ti múwa si ara Farao.

13. OLUWA si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Mose; awọn ọpọlọ na si kú kuro ninu ile, ninu agbalá, ati kuro ninu oko.

14. Nwọn si kó wọn jọ li òkiti-òkiti: ilẹ na si nrùn.

15. Ṣugbọn nigbati Farao ri pe isimi wà, o mu àiya rẹ̀ le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.

16. OLUWA si wi fun Mose pe, Sọ fun Aaroni pe, Nà ọpá rẹ, ki o si lù ekuru ilẹ, ki o le di iná já gbogbo ilẹ Egipti.

17. Nwọn si ṣe bẹ̃; Aaroni si nà ọwọ́ rẹ̀ pẹlu ọpá rẹ̀, o si lù erupẹ ilẹ, iná si wà lara enia, ati lara ẹran; gbogbo ekuru ilẹ li o di iná já gbogbo ilẹ Egipti.

18. Awọn alalupayida si fi idán wọn ṣe bẹ̃ lati mú iná jade wá, ṣugbọn nwọn kò le ṣe e: bẹ̃ni iná si wà lara enia, ati lara ẹran.

19. Nigbana ni awọn alalupayida wi fun Farao pe, Ika Ọlọrun li eyi: ṣugbọn àiya Farao le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.

20. OLUWA si wi fun Mose pe, Dide ni kutukutu owurọ̀, ki o si duro niwaju Farao; kiyesi i, o njade lọ si odò; ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi.

Ka pipe ipin Eks 8