Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 8:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose pe, Tọ̀ Farao lọ, ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA wipe, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi.

2. Bi iwọ ba si kọ̀ lati jẹ ki nwọn ki o lọ, kiyesi i, emi o fi ọpọlọ kọlù gbogbo ẹkùn rẹ:

3. Odò yio si bi ọpọlọ jade li ọ̀pọlọpọ, nwọn o si goke, nwọn o si wá sinu ile rẹ, ati sinu ibùsun rẹ, ati sori akete rẹ, ati sinu ile awọn ọmọ-ọdọ rẹ, ati sara awọn enia rẹ, ati sinu ãro rẹ, ati sinu ọpọ́n ìpo-iyẹfun rẹ:

4. Awọn ọpọlọ na yio si gùn ọ lara, ati lara awọn enia rẹ, ati lara gbogbo awọn iranṣẹ rẹ.

5. OLUWA si sọ fun Mose pe, Wi fun Aaroni pe, Nà ọwọ́ rẹ pẹlu ọpá rẹ sori odò wọnni, sori omi ṣiṣàn, ati sori ikojọpọ̀ omi, ki o si mú ọpọlọ jade wá sori ilẹ Egipti.

6. Aaroni si nà ọwọ́ rẹ̀ sori omi Egipti; awọn ọpọlọ si goke wá, nwọn si bò ilẹ Egipti.

7. Awọn alalupayida si fi idán wọn ṣe bẹ̃, nwọn si mú ọpọlọ jade wá sori ilẹ Egipti.

Ka pipe ipin Eks 8