Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 4:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. MOSE si dahùn o si wipe, Ṣugbọn kiyesi i, nwọn ki yio gbà mi gbọ́, bẹ̃ni nwọn ki yio fetisi ohùn mi: nitoriti nwọn o wipe, OLUWA kò farahàn ọ.

2. OLUWA si wi fun u pe, Kini wà li ọwọ́ rẹ nì? On si wipe, Ọpá ni.

3. O si wi fun u pe, Sọ ọ si ilẹ. On si sọ ọ si ilẹ, o si di ejò; Mose si sá kuro niwaju rẹ̀.

4. OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ ki o si mú u ni ìru: (On si nà ọwọ́ rẹ̀, o si mú u, o si di ọpá si i li ọwọ́:)

5. Ki nwọn ki o le gbàgbọ́ pe, OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu, li o farahàn ọ.

6. OLUWA si tun wi fun u pe, Fi ọwọ́ rẹ bọ̀ àiya rẹ. O si fi ọwọ́ rẹ̀ bọ̀ àiya rẹ̀: nigbati o si fà a yọ jade, si kiyesi i, ọwọ́ rẹ̀ dẹ́tẹ̀, o fún bi ẹ̀gbọn owu.

7. O si wipe, Tun fi ọwọ́ rẹ bọ̀ àiya rẹ. (O si tun fi ọwọ́ rẹ̀ bọ̀ àiya rẹ̀; o si fà a yọ jade li àiya rẹ̀; si kiyesi i, o si pada bọ̀ bi ẹran ara rẹ̀.)

8. Yio si ṣe, bi nwọn kò ba gbà ọ gbọ́, ti nwọn kò si fetisi ohùn iṣẹ-àmi iṣaju, njẹ nwọn o gbà ohùn iṣẹ-àmi ikẹhin gbọ́.

9. Yio si ṣe, bi nwọn kò ba si gbà àmi mejeji yi gbọ́ pẹlu, ti nwọn kò si fetisi ohùn rẹ, njẹ ki iwọ ki o bù ninu omi odò nì, ki o si dà a si iyangbẹ ilẹ: omi na ti iwọ bù ninu odò yio di ẹ̀jẹ ni iyangbẹ ilẹ.

10. Mose si wi fun OLUWA pe, Oluwa, emi ki iṣe ẹni ọ̀rọ-sisọ nigba atijọ wá, tabi lati igbati o ti mbá iranṣẹ rẹ sọ̀rọ: ṣugbọn olohùn wuwo ni mi, ati alahọn wuwo.

Ka pipe ipin Eks 4