Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 35:3-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Ẹnyin kò gbọdọ da iná ni ile nyin gbogbo li ọjọ́ isimi.

4. Mose si sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli pe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ, wipe,

5. Ẹnyin mú ọrẹ wá lati inu ara nyin fun OLUWA: ẹnikẹni ti ọkàn rẹ̀ fẹ́, ki o mú u wá, li ọrẹ fun OLUWA; wurà, ati fadakà, ati idẹ;

6. Ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ didara, ati irun ewurẹ;

7. Ati awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati awọ seali, ati igi ṣittimu;

8. Ati oróro fun fitila, ati olõrùn fun oróro itasori, ati fun turari didùn;

9. Ati okuta oniki, ati okuta ti a o tò si ẹ̀wu-efodi, ati si igbàiya.

10. Gbogbo ọlọgbọ́n inú ninu nyin yio si wá, yio si wá ṣiṣẹ gbogbo ohun ti OLUWA palaṣẹ;

11. Ibugbé na, ti on ti agọ́ rẹ̀, ati ibori rẹ̀, kọkọrọ rẹ̀, ati apáko rẹ̀, ọpá rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀;

12. Apoti nì, ati ọpá rẹ̀, itẹ́-ãnu nì, ati aṣọ-ikele na;

13. Tabili na, ati ọpá rẹ̀, ati ohun-èlo rẹ̀ gbogbo, ati àkara ifihàn nì;

14. Ati ọpà-fitila na fun titanna, ati ohun-elo rẹ̀, ati fitila rẹ̀, pẹlu oróro fun titanna.

Ka pipe ipin Eks 35