Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 30:3-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Iwọ o si fi kìki wurà bò o, oke rẹ̀, ati ìha rẹ̀ yiká, ati iwo rẹ̀; iwọ o si ṣe igbáti wurà yi i ká.

4. Ati oruka wurà meji ni ki iwọ ki o ṣe nisalẹ igbáti rẹ̀, ni ìha igun rẹ̀ meji, li ẹgbẹ rẹ̀ mejeji ni ki iwọ ki o ṣe e si; nwọn o si jasi ipò fun ọpá wọnni, lati ma fi gbé e.

5. Iwọ o si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, iwọ o si fi wurà bò wọn.

6. Iwọ o si gbé e kà iwaju aṣọ-ikele nì ti o wà lẹba apoti ẹrí, niwaju itẹ́-ãnu ti o wà lori apoti ẹrí nì, nibiti emi o ma bá ọ pade.

7. Aaroni yio si ma jó turari didùn lori rẹ̀; li orowurọ̀, nigbati o ba tun fitila wọnni ṣe, on o si ma jó o lori rẹ̀.

8. Nigbati Aaroni ba si tàn fitila wọnni li aṣalẹ, yio si ma jó turari lori rẹ̀, turari titilai niwaju OLUWA lati irandiran nyin.

9. Ẹnyin kò gbọdọ mú ajeji turari wá sori rẹ̀, tabi ẹbọ sisun, tabi ẹbọ onjẹ: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ dà ẹbọ ohun mimu sori rẹ̀.

10. Aaroni yio si ma fi ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ ètutu ṣètutu lori iwo rẹ̀ lẹ̃kan li ọdún: yio ṣètutu lori rẹ̀ lẹ̃kan li ọdun lati irandiran nyin: mimọ́ julọ ni si OLUWA.

11. OLUWA si sọ fun Mose pe,

12. Nigbati iwọ ba kà iye awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi ẹgbẹ wọn, nigbana li olukuluku ọkunrin yio mú irapada ọkàn rẹ̀ fun OLUWA wá, nigbati iwọ ba kà iye wọn; ki ajakalẹ-àrun ki o máṣe si ninu wọn, nigbati iwọ ba nkà iye wọn.

13. Eyi ni nwọn o múwa, olukuluku ẹniti o ba kọja sinu awọn ti a kà, àbọ ṣekeli, ani ṣekeli ibi mimọ́: (ogún gera ni ṣekeli kan:) àbọ ṣekeli li ọrẹ fun OLUWA.

14. Olukuluku ẹniti o ba kọja sinu awọn ti a kà, lati ẹni ogún ọdún ati jù bẹ̃ lọ, ni yio fi ọrẹ fun OLUWA.

Ka pipe ipin Eks 30