Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 30:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. IWỌ o si ṣe pẹpẹ kan lati ma jó turari lori rẹ̀: igi ṣittimu ni ki iwọ ki o fi ṣe e.

2. Igbọnwọ kan ni gigùn rẹ̀, ati igbọnwọ kan ni ibú rẹ̀; ìha mẹrin ọgbọgba ni ki o jẹ́: igbọnwọ meji si ni giga rẹ̀: iwo rẹ̀ yio si wà lara rẹ̀.

3. Iwọ o si fi kìki wurà bò o, oke rẹ̀, ati ìha rẹ̀ yiká, ati iwo rẹ̀; iwọ o si ṣe igbáti wurà yi i ká.

4. Ati oruka wurà meji ni ki iwọ ki o ṣe nisalẹ igbáti rẹ̀, ni ìha igun rẹ̀ meji, li ẹgbẹ rẹ̀ mejeji ni ki iwọ ki o ṣe e si; nwọn o si jasi ipò fun ọpá wọnni, lati ma fi gbé e.

5. Iwọ o si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, iwọ o si fi wurà bò wọn.

6. Iwọ o si gbé e kà iwaju aṣọ-ikele nì ti o wà lẹba apoti ẹrí, niwaju itẹ́-ãnu ti o wà lori apoti ẹrí nì, nibiti emi o ma bá ọ pade.

Ka pipe ipin Eks 30