Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 22:6-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Bi iná ba ṣẹ̀, ti o si mu ẹwọn, ti abà ọkà, tabi ọkà aiṣá, tabi oko li o joná; ẹniti o ràn iná na yio san ẹsan nitõtọ.

7. Bi ẹnikan ba fi owo tabi ohunèlo fun ẹnikeji rẹ̀ pamọ́; ti a ji i ni ile ọkunrin na; bi a ba mu olè na, ki o san a ni meji.

8. Bi a kò ba mú olè na, njẹ ki a mú bale na wá siwaju awọn onidajọ, bi on kò ba fọwọkàn ẹrù ẹnikeji rẹ̀.

9. Nitori irú ẹ̀ṣẹ gbogbo, iba ṣe ti akọmalu, ti kẹtẹkẹtẹ, ti agutan, ti aṣọ, tabi ti irũru ohun ti o nù, ti ẹlomiran pè ni ti on, ẹjọ́ awọn mejeji yio wá siwaju awọn onidajọ; ẹniti awọn onidajọ ba dẹbi fun, on o san a ni iṣẹmeji fun ẹnikeji rẹ̀.

10. Bi enia ba fi kẹtẹkẹtẹ, tabi akọmalu, tabi agutan, tabi ẹrankẹran lé ẹnikeji rẹ̀ lọwọ lati ma sìn; ti o ba si kú, tabi ti o farapa, tabi ti a lé e sọnù, ti ẹnikan kò ri i;

11. Ibura OLUWA yio wà lãrin awọn mejeji, pe, on kò fọwọkàn ẹrù ẹnikeji on; ki on ki o si gbà, on ki yio si san ẹsan.

12. Bi o ba ṣepe a ji i lọwọ rẹ̀, on o san ẹsan fun oluwa rẹ̀.

13. Bi o ba ṣepe a si fà a ya, njẹ ki o mú u wa ṣe ẹrí, on ki yio si san ẹsan eyiti a fàya.

14. Bi enia ba si yá ohun kan lọwọ ẹnikeji rẹ̀, ti o si farapa, tabi ti o kú, ti olohun kò si nibẹ̀, on o san ẹsan nitõtọ.

15. Ṣugbọn bi olohun ba wà nibẹ̀, on ki yio san ẹsan: bi o ba ṣe ohun ti a fi owo gbà lò ni, o dé fun owo igbàlo rẹ̀.

16. Bi ọkunrin kan ba si tàn wundia kan ti a kò ti ifẹ́, ti o si mọ̀ ọ, fifẹ́ ni yio si fẹ́ ẹ li aya rẹ̀.

17. Bi baba rẹ̀ ba kọ̀ jalẹ lati fi i fun u, on o san ojì gẹgẹ bi ifẹ́ wundia.

18. Iwọ kò gbọdọ jẹ ki ajẹ́ ki o wà lãye.

Ka pipe ipin Eks 22