Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 22:16-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Bi ọkunrin kan ba si tàn wundia kan ti a kò ti ifẹ́, ti o si mọ̀ ọ, fifẹ́ ni yio si fẹ́ ẹ li aya rẹ̀.

17. Bi baba rẹ̀ ba kọ̀ jalẹ lati fi i fun u, on o san ojì gẹgẹ bi ifẹ́ wundia.

18. Iwọ kò gbọdọ jẹ ki ajẹ́ ki o wà lãye.

19. Ẹnikẹni ti o ba bá ẹranko dàpọ pipa li a o pa a.

20. Ẹnikẹni ti o ba rubọ si oriṣakoriṣa, bikoṣe si JEHOFA nikanṣoṣo, a o pa a run tútu.

21. Iwọ kò gbọdọ ṣìka si alejò, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ni i lara: nitoripe alejò li ẹnyin ti jẹ́ ni ilẹ Egipti.

22. Ẹnyin kò gbọdọ jẹ opó ni ìya, tabi ọmọ alainibaba.

23. Bi iwọ ba jẹ wọn ni ìyakiya, ti nwọn si kigbe pè mi, emi o gbọ́ igbe wọn nitõtọ.

24. Ibinu mi yio si gboná, emi o si fi idà pa nyin; awọn aya nyin yio si di opó, awọn ọmọ nyin a si di alainibaba.

25. Bi iwọ ba yá ẹnikẹni ninu awọn enia mi li owo ti o ṣe talaka lọdọ rẹ, iwọ ki yio jẹ́ bi agbẹ̀da fun u; bẹ̃ni iwọ ki yio gbẹ̀da lọwọ rẹ̀.

26. Bi o ba ṣepe iwọ gbà aṣọ ẹnikeji rẹ ṣe ògo, ki iwọ ki o si fi i fun u, ki õrùn to wọ̀:

27. Nitori kìki eyi ni ibora rẹ̀, aṣọ rẹ̀ ti yio fi bora ni: kini on o fi bora sùn? yio si ṣe bi o ba kigbe pè mi, emi o gbọ́; nitori alãnu li emi.

28. Iwọ kò gbọdọ gàn awọn onidajọ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bú ijoye kan ninu awọn enia rẹ.

29. Iwọ kò gbọdọ jafara lati mú irè oko rẹ wá, ati ọti rẹ. Akọ́bi awọn ọmọ rẹ ọkunrin ni iwọ o fi fun mi.

30. Bẹ̃ gẹgẹ ni ki iwọ ki o fi akọmalu ati agutan rẹ ṣe: ijọ́ meje ni ki o ba iya rẹ̀ gbọ́; ni ijọ́ kẹjọ ni ki iwọ ki o fi i fun mi.

31. Ẹnyin o si jẹ́ enia mimọ́ fun mi; nitorina ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹran ti a ti ọwọ ẹranko igbẹ́ fàya; ajá ni ki ẹnyin ki o wọ́ ọ fun.

Ka pipe ipin Eks 22