Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 22:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BI ọkunrin kan ba ji akọmalu, tabi agutan kan, ti o si pa a, tabi ti o tà a; yio san akọmalu marun dipò akọmalu kan, ati agutan mẹrin dipò agutan kan.

2. Bi a ba ri olè ti nrunlẹ wọle, ti a si lù u ti o kú, a ki yio ta ẹ̀jẹ silẹ fun u.

3. Bi õrùn ba là bá a, a o ta ẹ̀jẹ silẹ fun u; sisan li on iba san; bi kò ni nkan, njẹ a o tà a nitori olè rẹ̀.

4. Bi a ba ri ohun ti o ji na li ọwọ́ rẹ̀ nitõtọ li ãye, iba ṣe akọmalu, tabi kẹtẹkẹtẹ, tabi agutan; on o san a pada ni meji.

5. Bi ọkunrin kan ba mu ki a jẹ oko tabi agbalá-àjara kan, ti o si tú ẹran rẹ̀ silẹ, ti o si jẹ li oko ẹlomiran; ninu ãyo oko ti ara rẹ̀, ati ninu ãyo agbalá-àjara tirẹ̀, ni yio fi san ẹsan.

6. Bi iná ba ṣẹ̀, ti o si mu ẹwọn, ti abà ọkà, tabi ọkà aiṣá, tabi oko li o joná; ẹniti o ràn iná na yio san ẹsan nitõtọ.

7. Bi ẹnikan ba fi owo tabi ohunèlo fun ẹnikeji rẹ̀ pamọ́; ti a ji i ni ile ọkunrin na; bi a ba mu olè na, ki o san a ni meji.

8. Bi a kò ba mú olè na, njẹ ki a mú bale na wá siwaju awọn onidajọ, bi on kò ba fọwọkàn ẹrù ẹnikeji rẹ̀.

9. Nitori irú ẹ̀ṣẹ gbogbo, iba ṣe ti akọmalu, ti kẹtẹkẹtẹ, ti agutan, ti aṣọ, tabi ti irũru ohun ti o nù, ti ẹlomiran pè ni ti on, ẹjọ́ awọn mejeji yio wá siwaju awọn onidajọ; ẹniti awọn onidajọ ba dẹbi fun, on o san a ni iṣẹmeji fun ẹnikeji rẹ̀.

10. Bi enia ba fi kẹtẹkẹtẹ, tabi akọmalu, tabi agutan, tabi ẹrankẹran lé ẹnikeji rẹ̀ lọwọ lati ma sìn; ti o ba si kú, tabi ti o farapa, tabi ti a lé e sọnù, ti ẹnikan kò ri i;

11. Ibura OLUWA yio wà lãrin awọn mejeji, pe, on kò fọwọkàn ẹrù ẹnikeji on; ki on ki o si gbà, on ki yio si san ẹsan.

12. Bi o ba ṣepe a ji i lọwọ rẹ̀, on o san ẹsan fun oluwa rẹ̀.

13. Bi o ba ṣepe a si fà a ya, njẹ ki o mú u wa ṣe ẹrí, on ki yio si san ẹsan eyiti a fàya.

14. Bi enia ba si yá ohun kan lọwọ ẹnikeji rẹ̀, ti o si farapa, tabi ti o kú, ti olohun kò si nibẹ̀, on o san ẹsan nitõtọ.

Ka pipe ipin Eks 22