Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 20:5-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Iwọ kò gbọdọ tẹ̀ ori ara rẹ ba fun wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitori emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owú ni mi, ti mbẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, lati irandiran kẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi;

6. Emi a si ma fi ãnu hàn ẹgbẹgbẹrun awọn ti o fẹ́ mi, ti nwọn si npa ofin mi mọ́.

7. Iwọ kò gbọdọ pè orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ lasan; nitoriti OLUWA ki yio mu awọn ti o pè orukọ rẹ̀ lasan bi alailẹ̀ṣẹ li ọrùn.

8. Ranti ọjọ́ isimi, lati yà a simimọ́.

9. Ọjọ́ mẹfa ni iwọ o ṣiṣẹ, ti iwọ o si ṣe iṣẹ rẹ gbogbo:

10. Ṣugbọn ọjọ́ keje li ijọ́ isimi OLUWA Ọlọrun rẹ: ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ohunọ̀sin rẹ, ati alejò rẹ̀ ti mbẹ ninu ibode rẹ:

11. Nitori ni ijọ́ mẹfa li OLUWA dá ọrun on aiye, okun ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn, o si simi ni ijọ́ keje: nitorina li OLUWA ṣe busi ijọ́ keje, o si yà a si mimọ́.

12. Bọ̀wọ fun baba on iya rẹ: ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.

13. Iwọ kò gbọdọ pania.

Ka pipe ipin Eks 20