Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 16:9-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Mose si sọ fun Aaroni pe, Sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ sunmọ iwaju OLUWA, nitoriti o ti gbọ́ kikùn nyin.

10. O si ṣe, nigbati Aaroni nsọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, nwọn si bojuwò ìha ijù, si kiyesi i, ogo OLUWA hàn li awọsanma na.

11. OLUWA si sọ fun Mose pe,

12. Emi ti gbọ́ kikùn awọn ọmọ Israeli: sọ fun wọn pe, Li aṣalẹ ẹnyin o jẹ ẹran, ati li owurọ̀ a o si fi onjẹ kún nyin; ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

13. O si ṣe li aṣalẹ ni aparò fò dé, nwọn si bò ibudó mọlẹ; ati li owurọ̀ ìri si sẹ̀ yi gbogbo ibudó na ká.

14. Nigbati ìri ti o sẹ̀ bolẹ si fà soke, si kiyesi i, lori ilẹ ijù na, ohun ribiribi, o kere bi ìri didì li ori ilẹ.

15. Nigbati awọn ọmọ Israeli si ri i, nwọn wi fun ara wọn pe, Kili eyi? nitoriti nwọn kò mọ̀ ohun na. Mose si wi fun wọn pe, Eyi li onjẹ ti OLUWA fi fun nyin lati jẹ.

Ka pipe ipin Eks 16