Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 12:36-49 Yorùbá Bibeli (YCE)

36. OLUWA si fun awọn enia na li ojurere li oju awọn ara Egipti, bẹ̃ni nwọn si fun wọn li ohun ti nwọn bère. Nwọn si kó ẹrù awọn ara Egipti.

37. Awọn ọmọ Israeli si rìn lati Ramesesi lọ si Sukkotu, nwọn to ìwọn ọgbọ̀n ọkẹ ẹlẹsẹ̀ ọkunrin, li àika ọmọde.

38. Ati ọ̀pọ enia ti o dàpọ mọ́ wọn bá wọn goke lọ pẹlu; ati agbo, ati ọwọ́-ẹran, ani ọ̀pọlọpọ ẹran.

39. Nwọn si yan àkara iyẹfun pipò alaiwu ti nwọn mú jade ti Egipti wá, nwọn kò sa fi iwukàra si i; nitoriti a tì wọn jade kuro ni Egipti, nwọn kò si le duro, bẹ̃ni nwọn kò pèse ohun jijẹ kan fun ara wọn.

40. Njẹ ìgba atipo awọn ọmọ Israeli ti nwọn ṣe ni ilẹ Egipti, o jẹ́ irinwo ọdún o le ọgbọ̀n.

41. O si ṣe li opin irinwo ọdún o le ọgbọ̀n, ani li ọjọ́ na gan, li o si ṣe ti gbogbo ogun OLUWA jade kuro ni ilẹ Egipti.

42. Oru ti a ikiyesi ni gidigidi si OLUWA ni mimú wọn jade kuro ni ilẹ Egipti: eyi li oru ti a ikiyesi si OLUWA, li ati irandiran gbogbo awọn ọmọ Israeli.

43. OLUWA si wi fun Mose ati Aaroni pe, Eyi ni ìlana irekọja: alejokalejò ki yio jẹ ninu rẹ̀:

44. Ṣugbọn iranṣẹ ẹnikẹni ti a fi owo rà, nigbati iwọ ba kọ ọ nilà, nigbana ni ki o jẹ ninu rẹ̀.

45. Alejò ati alagbaṣe ki yio jẹ ninu rẹ̀.

46. Ni ile kan li a o jẹ ẹ; iwọ kò gbọdọ mú ninu ẹran rẹ̀ jade sode kuro ninu ile na; bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fọ́ ọkan ninu egungun rẹ̀.

47. Gbogbo ijọ Israeli ni yio ṣe e.

48. Nigbati alejò kan ba nṣe atipo lọdọ rẹ, ti o si nṣe ajọ irekọja si OLUWA, ki a kọ gbogbo ọkunrin rẹ̀ nilà, nigbana ni ki ẹ jẹ ki o sunmọtosi, ki o si ṣe e; on o si dabi ẹniti a bi ni ilẹ na: nitoriti kò si ẹni alaikọlà ti yio jẹ ninu rẹ̀.

49. Ofin kan ni fun ibilẹ ati fun alejò ti o ṣe atipo ninu nyin.

Ka pipe ipin Eks 12