Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 12:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni ni ilẹ Egipti pe,

2. Oṣù yi ni yio ṣe akọ́kà oṣù fun nyin: on ni yio ṣe ekini oṣù ọdún fun nyin.

3. Ẹ sọ fun gbogbo ijọ awọn enia Israeli pe, Ni ijọ́ kẹwa oṣù yi ni ki olukuluku wọn ki o mú ọdọ-agutan sọdọ, gẹgẹ bi ile baba wọn, ọdọ-agutan kan fun ile kan:

4. Bi awọn ara ile na ba si kere jù ìwọn ọdọ-agutan na lọ, ki on ati aladugbo rẹ̀ ti o sunmọ-eti ile rẹ̀, ki o mú gẹgẹ bi iye awọn ọkàn na, olukuluku ni ìwọn ijẹ rẹ̀ ni ki ẹ ṣiro ọdọ-agutan na.

5. Ailabùku ni ki ọdọ-agutan nyin ki o jẹ́, akọ ọlọdún kan: ẹnyin o mú u ninu agutan, tabi ninu ewurẹ:

6. Ẹnyin o si fi i pamọ́ titi o fi di ijọ́ kẹrinla oṣù na: gbogbo agbajọ ijọ Israeli ni yio pa a li aṣalẹ.

7. Nwọn o si mú ninu ẹ̀jẹ na, nwọn o si fi tọ́ ara opó ìha mejeji, ati sara atẹrigba ile wọnni, ninu eyiti nwọn o jẹ ẹ.

8. Nwọn o si jẹ ẹran na ti a fi iná sun li oru na, ati àkara alaiwu; ewebẹ kikorò ni nwọn o fi jẹ ẹ.

9. Ẹ máṣe jẹ ninu rẹ̀ ni tutù, tabi ti a fi omi bọ̀, bikoṣepe sisun ninu iná; ati ori rẹ̀, ati itan rẹ̀, ati akopọ̀ inu rẹ̀ pẹlu.

10. Ẹ kò si gbọdọ jẹ ki nkan ki o kù silẹ ninu rẹ̀ dé ojumọ́; eyiti o ba si kù di ijọ́ keji on ni ki ẹnyin ki o daná sun.

11. Bayi li ẹnyin o si jẹ ẹ; ti ẹnyin ti àmure didì li ẹgbẹ nyin, bàta nyin li ẹsẹ̀ nyin, ati ọpá nyin li ọwọ́ nyin, ẹnyin o si yara jẹ ẹ: irekọja OLUWA ni.

12. Nitoriti emi o là ilẹ Egipti já li oru na, emi o si kọlù gbogbo awọn akọ́bi ni ilẹ Egipti, ti enia ati ti ẹran; ati lara gbogbo oriṣa Egipti li emi o ṣe idajọ: emi li OLUWA.

Ka pipe ipin Eks 12