Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹk. Jer 2:14-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Awọn woli rẹ ti riran ohun asan ati wère fun ọ: nwọn kò si ti fi aiṣedede rẹ hàn ọ, lati yi igbekun rẹ pada kuro; ṣugbọn nwọn ti riran ọ̀rọ-wiwo eke fun ọ ati imuniṣina.

15. Gbogbo awọn ti nkọja patẹwọ le ọ; nwọn nṣẹsin, nwọn si nmì ori wọn si ọmọbinrin Jerusalemu; pe, Ilu na ha li eyi, ti a npè ni: Pipe-ẹwà, Ayọ̀ gbogbo ilẹ aiye!

16. Gbogbo awọn ọta rẹ ya ẹnu wọn si ọ; nwọn nṣe ṣiọ! nwọn si npa ehin keke, nwọn wipe: Awa ti gbe e mì; dajudaju eyi li ọjọ na ti awa ti nwọ̀na fun; ọwọ ti tẹ̀ ẹ, awa ti ri i!

17. Oluwa ti ṣe eyi ti o ti rò; o ti mu ọrọ rẹ̀ ṣẹ ti o ti paṣẹ li ọjọ igbãni: o ti bì ṣubu, kò si dasi: o si ti mu ọta yọ̀ lori rẹ, o ti gbe iwo awọn aninilara rẹ soke.

18. Ọkàn wọn kigbe si Oluwa, iwọ odi ọmọbinrin Sioni, jẹ ki omije ṣan silẹ gẹgẹ bi odò lọsan ati loru; má fun ara rẹ ni isimi; máṣe jẹ ki ẹyin oju rẹ gbe jẹ.

19. Dide, kigbe soke li oru ni ibẹrẹ akoko iṣọ: tú ọkàn rẹ jade gẹgẹ bi omi niwaju Oluwa: gbe ọwọ rẹ soke si i fun ẹmi awọn ọmọ wẹwẹ rẹ, ti nkulọ fun ebi ni gbogbo ori-ita.

20. Wò o, Oluwa, ki o rò, fun tani iwọ ti ṣe eyi? Awọn obinrin ha le ma jẹ eso-inu wọn, awọn ọmọ-ọwọ ti nwọn npọ̀n? a ha le ma pa alufa ati woli ni ibi mimọ́ Oluwa?

21. Ewe ati arugbo dubulẹ ni ita wọnni: awọn wundia mi ati awọn ọdọmọkunrin mi ṣubu nipa idà: iwọ ti pa li ọjọ ibinu rẹ; iwọ ti pa, iwọ kò si dasi.

22. Iwọ ti kepe ẹ̀ru mi yikakiri gẹgẹ bi li ọjọ mimọ́, tobẹ̃ ti ẹnikan kò sala tabi kì o kù li ọjọ ibinu Oluwa: awọn ti mo ti pọ̀n ti mo si tọ́, ni ọta mi ti run.

Ka pipe ipin Ẹk. Jer 2