Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹk. Jer 2:11-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Oju mi gbẹ tan fun omije, inu mi nho, a dà ẹ̀dọ mi sori ilẹ, nitori iparun ọmọbinrin awọn enia mi: nitoripe awọn ọmọ wẹ̃rẹ ati awọn ọmọ-ọmu nkulọ ni ita ilu na.

12. Nwọn nsọ fun iya wọn pe, Nibo ni ọka ati ọti-waini gbe wà? nigbati nwọn daku gẹgẹ bi awọn ti a ṣalọgbẹ ni ita ilu na, nigbati ọkàn wọn dà jade li aiya iya wọn.

13. Kili ohun ti emi o mu fi jẹri niwaju rẹ? kili ohun ti emi o fi ọ we, iwọ ọmọbinrin Jerusalemu? kili emi o fi ba ọ dọgba, ki emi ba le tù ọ ninu, iwọ wundia ọmọbinrin Sioni? nitoripe ọgbẹ rẹ tobi gẹgẹ bi okun; tali o le wò ọ sàn?

14. Awọn woli rẹ ti riran ohun asan ati wère fun ọ: nwọn kò si ti fi aiṣedede rẹ hàn ọ, lati yi igbekun rẹ pada kuro; ṣugbọn nwọn ti riran ọ̀rọ-wiwo eke fun ọ ati imuniṣina.

15. Gbogbo awọn ti nkọja patẹwọ le ọ; nwọn nṣẹsin, nwọn si nmì ori wọn si ọmọbinrin Jerusalemu; pe, Ilu na ha li eyi, ti a npè ni: Pipe-ẹwà, Ayọ̀ gbogbo ilẹ aiye!

16. Gbogbo awọn ọta rẹ ya ẹnu wọn si ọ; nwọn nṣe ṣiọ! nwọn si npa ehin keke, nwọn wipe: Awa ti gbe e mì; dajudaju eyi li ọjọ na ti awa ti nwọ̀na fun; ọwọ ti tẹ̀ ẹ, awa ti ri i!

17. Oluwa ti ṣe eyi ti o ti rò; o ti mu ọrọ rẹ̀ ṣẹ ti o ti paṣẹ li ọjọ igbãni: o ti bì ṣubu, kò si dasi: o si ti mu ọta yọ̀ lori rẹ, o ti gbe iwo awọn aninilara rẹ soke.

18. Ọkàn wọn kigbe si Oluwa, iwọ odi ọmọbinrin Sioni, jẹ ki omije ṣan silẹ gẹgẹ bi odò lọsan ati loru; má fun ara rẹ ni isimi; máṣe jẹ ki ẹyin oju rẹ gbe jẹ.

Ka pipe ipin Ẹk. Jer 2