Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dan 9:17-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Njẹ nitorina, Ọlọrun wa, gbọ́ adura ọmọ-ọdọ rẹ, ati ẹ̀bẹ rẹ̀, ki o si mu ki oju rẹ ki o mọlẹ si ibi-mimọ́ rẹ ti o dahoro, nitori ti Oluwa.

18. Tẹ eti rẹ silẹ, Ọlọrun mi, ki o si gbọ́: ṣi oju rẹ, ki o si wò idahoro wa, ati ilu ti a nfi orukọ rẹ pè: nitoriti awa kò gbé ẹ̀bẹ wa kalẹ niwaju rẹ nitori ododo wa, ṣugbọn nitori ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ nla.

19. Oluwa, gbọ́, Oluwa, dariji: Oluwa, tẹ eti rẹ silẹ ki o si ṣe; máṣe jafara, nitori ti iwọ tikararẹ, Ọlọrun mi: nitori orukọ rẹ li a fi npè ilu rẹ, ati awọn enia rẹ.

20. Bi emi si ti nwi, ti emi ngbadura, ati bi emi si ti njẹwọ ẹṣẹ mi, ati ẹ̀ṣẹ Israeli awọn enia mi, ti emi si ngbé ẹbẹ mi kalẹ niwaju Oluwa, Ọlọrun mi, nitori òke mimọ́ Ọlọrun mi.

21. Bẹni, bi mo ti nwi lọwọ ninu adura mi, ọkunrin na, Gabrieli ti mo ti ri ni iran mi li atetekọṣe, li a mu lati fò wá kankan, o de ọdọ mi niwọn akokò ẹbọ aṣãlẹ.

22. O mu mi mọ̀, o si mba mi sọ̀rọ wipe, Danieli, mo jade wá nisisiyi lati fi oye fun ọ.

23. Ni ipilẹṣẹ ẹ̀bẹ rẹ li ọ̀rọ ti jade wá, emi si wá lati fi hàn fun ọ, nitoriti iwọ iṣe ayanfẹ gidigidi: nitorina, moye ọ̀ran na, ki o si kiyesi iran na.

24. Adọrin ọ̀sẹ li a pinnu sori awọn enia rẹ, ati sori ilu mimọ́ rẹ, lati ṣe ipari irekọja, ati lati fi edidi di ẹ̀ṣẹ, ati lati ṣe ilaja fun aiṣedẽde ati lati mu ododo ainipẹkun wá ati lati ṣe edidi iran ati woli, ati lati fi ororo yàn Ẹni-mimọ́ julọ nì.

Ka pipe ipin Dan 9