Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dan 4:16-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Ki a si pa aiya rẹ̀ da kuro ni ti enia, ki a si fi aiya ẹranko fun u, ki igba meje ki o si kọja lori rẹ̀.

17. Nipa ọ̀rọ lati ọdọ awọn oluṣọ li ọ̀ran yi, ati aṣẹ nipa ọ̀rọ awọn ẹni mimọ́ nì; nitori ki awọn alàye ki o le mọ̀ pe Ọga-ogo li o nṣe olori ni ijọba enia, on a si fi fun ẹnikẹni ti o wù u, on a si gbé onirẹlẹ julọ leke lori rẹ̀.

18. Alá yi li emi Nebukadnessari lá, njẹ nisisiyi, iwọ Belteṣassari, sọ itumọ rẹ̀ fun mi, bi gbogbo awọn ọlọgbọ́n ijọba mi kò ti le fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi: ṣugbọn iwọ le ṣe e; nitori ẹmi Ọlọrun mimọ́ mbẹ lara rẹ.

19. Nigbana ni Danieli, ẹniti a npè ni Belteṣassari wà ni ìwariri niwọn wakati kan, ìro-inu rẹ̀ si dãmu rẹ̀. Ọba si dahùn wipe, Belteṣassari, máṣe jẹ ki alá na, tabi itumọ rẹ̀ ki o dãmu rẹ̀. Belteṣassari si dahùn wipe, oluwa mi! ti awọn ẹniti o korira rẹ li alá yi, ki itumọ rẹ̀ ki o si jẹ ti awọn ọta rẹ.

20. Igi ti iwọ ri ti o si dagba, ti o si lagbara, eyi ti giga rẹ̀ kan ọrun, ti a si ri i de gbogbo aiye;

21. Eyi ti ewe rẹ̀ lẹwà, ti eso rẹ̀ si pọ̀, ninu eyi ti onjẹ si wà fun gbogbo ẹda, labẹ eyi ti awọn ẹranko igbẹ ngbe, lori ẹka eyi ti awọn ẹiyẹ oju-ọrun ni ibugbe wọn.

22. Ọba, iwọ ni ẹniti o dagba, ti o si di alagbara: nitori titobi rẹ ga o si kan ọrun, agbara ijọba rẹ si de opin aiye.

23. Ati gẹgẹ bi ọba si ti ri oluṣọ́ kan ani ẹni mimọ́ ti o sọkalẹ lati ọrun wá, ti o si wipe, Ke igi na lulẹ, ki o si pa a run: ṣugbọn fi kukute gbòngbo rẹ̀ silẹ lãye, ani ti on ti ìde irin ati ti idẹ, ninu koriko tutu igbẹ; ki a si jẹ ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, ki ipin rẹ̀ si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ, titi ìgba meje yio fi kọja lori rẹ̀,

24. Ọba, itumọ rẹ̀ li eyi, ati eyiyi li aṣẹ Ọga-ogo, ti o wá sori ọba, oluwa mi:

25. Nwọn o le ọ kuro larin enia, ibugbe rẹ yio si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ nwọn o si mu ki iwọ ki o jẹ koriko bi malu, nwọn o si mu ki iri ọrun sẹ̀ si ọ lara, igba meje yio si kọja lori rẹ, titi iwọ o fi mọ̀ pe Ọga-ogo ni iṣe olori ni ijọba enia, on a si fi i fun ẹnikẹni ti o wù u.

26. Ati gẹgẹ bi nwọn si ti paṣẹ pe ki nwọn ki o fi kukute gbòngbo igi na silẹ, ijọba rẹ yio jẹ tirẹ, lẹhin igbati o ba ti mọ̀ pe, ọrun ni iṣe olori.

27. Nitorina ọba, jẹ ki ìmọran mi ki o jẹ itẹwọgba lọdọ rẹ, ki o si fi ododo ja ẹ̀ṣẹ rẹ kuro, ati aiṣedẽde rẹ nipa fifi ãnu hàn fun awọn talaka; bi yio le mu alafia rẹ pẹ.

28. Gbogbo eyi de ba Nebukadnessari, ọba.

Ka pipe ipin Dan 4