Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dan 11:6-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Lẹhin ọdun pipọ nwọn o si kó ara wọn jọ pọ̀; ọmọbinrin ọba gusu yio wá sọdọ ọba ariwa, lati ba a dá majẹmu: ṣugbọn on kì yio le di agbara apá na mu; bẹ̃ni on kì yio le duro, tabi apá rẹ̀: ṣugbọn a o fi on silẹ, ati awọn ti o mu u wá, ati ẹni ti o bi i, ati ẹniti nmu u lọkàn le li akokò ti o kọja.

7. Ṣugbọn ninu ẹka gbòngbo rẹ̀ li ẹnikan yio dide ni ipò rẹ̀, ẹniti yio wá pẹlu ogun, yio si wọ̀ ilu-olodi ọba ariwa, yio si ba wọn ṣe, yio si bori.

8. On o si kó oriṣa wọn pẹlu ere didà wọn, ati ohunelo wọn daradara, ti fadaka, ati ti wura ni igbekun lọ si Egipti; on o si duro li ọdun melokan kuro lọdọ ọba ariwa.

9. On o si lọ si ijọba ọba gusu, ṣugbọn yio yipada si ilẹ ontikararẹ̀.

10. Ṣugbọn awọn ọmọ rẹ̀ yio ru soke, nwọn o si gbá ogun nla ọ̀pọlọpọ enia jọ; ẹnikan yio wọle wá, yio si bolẹ̀, yio si kọja lọ. Nigbana ni yio pada yio si gbé ogun lọ si ilu olodi rẹ̀.

11. Ọba gusu yio si fi ibinu ru soke, yio si jade wá ba a jà, ani, ọba ariwa na: on o si kó enia pipọ jọ; ṣugbọn a o fi ọ̀pọlọpọ na le e lọwọ.

12. Yio si kó ọ̀pọlọpọ na lọ, ọkàn rẹ̀ yio si gbé soke; on o si bì ọ̀pọlọpọ ẹgbãrun enia ṣubu; ṣugbọn a kì yio fi ẹsẹ rẹ̀ mulẹ nipa eyi.

13. Nitoripe ọba ariwa yio si yipada, yio si kó ọ̀pọlọpọ enia jọ ti yio pọ̀ jù ti iṣaju lọ, yio si wá lẹhin ọdun melokan pẹlu ogun nla, ati ọ̀pọlọpọ ọrọ̀.

14. Li akoko wọnni li ọ̀pọlọpọ yio si dide si ọba gusu; awọn ọlọ̀tẹ ninu awọn enia rẹ̀ yio si gbé ara wọn ga lati fi ẹsẹ iran na mulẹ pẹlu: ṣugbọn nwọn o ṣubu.

15. Bẹ̃li ọba ariwa yio si wá, yio si mọdi, yio si gbà ilu olodi; apá ogun ọba gusu kì yio le duro, ati awọn ayanfẹ enia rẹ̀, bẹ̃ni kì yio si agbara lati da a duro.

16. Ṣugbọn ẹniti o tọ̀ ọ wá yio mã ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu ara rẹ̀, kì yio si si ẹniti yio duro niwaju rẹ̀; on o si duro ni ilẹ daradara nì, ti yio si fi ọwọ rẹ̀ parun.

17. On o si gbé oju rẹ̀ soke lati wọ̀ ọ nipa agbara gbogbo ijọba rẹ̀, yio si ba a dá majẹmu, bẹ̃ni yio ṣe; on o si fi ọmọbinrin awọn obinrin fun u, lati bà a jẹ: ṣugbọn on kì yio duro, bẹ̃ni kì yio si ṣe tirẹ̀.

18. Lẹhin eyi, yio kọ oju rẹ̀ si erekuṣu wọnni, yio si gbà ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn balogun kan fun ara rẹ̀, yio fi opin si ẹ̀gan rẹ̀: ati nipò eyi, yio mu ẹ̀gan rẹ̀ pada wá sori ara rẹ̀.

19. Nigbana ni yio si yi oju rẹ̀ pada si ilu olodi ontikararẹ̀: ṣugbọn yio kọsẹ, yio si ṣubu, a kì yio si ri i mọ.

20. Nigbana ni ẹnikan yio dide ni ipò rẹ̀ ti yio mu agbowode kan rekọja ninu ogo ijọba (ilẹ Juda): ṣugbọn niwọn ijọ melokan li a o si pa a run, kì yio ṣe nipa ibinu tabi loju ogun.

21. Ni ipò rẹ̀ li enia lasan kan yio dide, ẹniti nwọn kì yio fi ọlá ọba fun: ṣugbọn yio wá lojiji, yio si fi arekereke gbà ijọba.

22. Ogun ti mbò ni mọlẹ li a o fi bò wọn mọlẹ niwaju rẹ̀, a o si fọ ọ tũtu, ati pẹlu ọmọ-alade majẹmu kan.

Ka pipe ipin Dan 11