Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dan 11:25-41 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Yio si rú agbara ati igboya rẹ̀ soke si ọba gusu ti on ti ogun nla; a o si rú ọba gusu soke si ija pẹlu ogun nlanla ati alagbara pupọ; ṣugbọn on kì yio le duro: nitori nwọn o gba èro tẹlẹ si i.

26. Awọn ẹniti o jẹ ninu adidùn rẹ̀ ni yio si pa a run, ogun rẹ̀ yio si tàn kalẹ; ọ̀pọlọpọ ni yio si ṣubu ni pipa.

27. Ọkàn awọn ọba mejeji wọnyi ni yio wà lati ṣe buburu, nwọn o si mã sọ̀rọ eké lori tabili kan, ṣugbọn kì yio jẹ rere; nitoripe opin yio wà li akokò ti a pinnu.

28. Nigbana ni yio pada lọ si ilẹ ontikararẹ̀ ti on ti ọrọ̀ pupọ: ọkàn rẹ̀ yio si lodi si majẹmu mimọ́ nì, yio ṣe e, yio si pada lọ si ilẹ ontikararẹ̀.

29. Yio si pada wá li akokò ti a pinnu, yio si wá si iha gusu; ṣugbọn kì yio ri bi ti iṣaju, ni ikẹhin.

30. Nitoripe ọkọ̀ awọn ara Kittimu yio tọ̀ ọ wá, nitorina ni yio ṣe dãmu, yio si yipada, yio si ni ibinu si majẹmu mimọ́ nì; bẹ̃ni yio ṣe; ani on o yipada, yio si tun ni idapọ pẹlu awọn ti o kọ̀ majẹmu mimọ́ na silẹ.

31. Agbara ogun yio si duro li apa tirẹ̀, nwọn o si sọ ibi mimọ́, ani ilu olodi na di aimọ́, nwọn o si mu ẹbọ ojojumọ kuro, nwọn o si gbé irira isọdahoro nì kalẹ.

32. Ati iru awọn ti nṣe buburu si majẹmu nì ni yio fi ọ̀rọ ipọnni mu ṣọ̀tẹ: ṣugbọn awọn enia ti o mọ̀ Ọlọrun yio mu ọkàn le, nwọn o si ma ṣe iṣẹ agbara.

33. Awọn ti o moye ninu awọn enia yio ma kọ́ ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn nwọn o ma ti ipa oju idà ṣubu, ati nipa iná, ati nipa igbekun, ati nipa ikogun nijọmelo kan.

34. Njẹ nisisiyi, nigbati nwọn o ṣubu, a o fi iranlọwọ diẹ ràn wọn lọwọ: ṣugbọn ọ̀pọlọpọ ni yio fi ẹ̀tan fi ara mọ́ wọn.

35. Awọn ẹlomiran ninu awọn ti o moye yio si ṣubu, lati dan wọn wò, ati lati wẹ̀ wọn mọ́, ati lati sọ wọn di funfun, ani titi fi di akokò opin: nitoripe yio wà li akokò ti a pinnu.

36. Ọba na yio si ma ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀; on o si gbé ara rẹ̀ ga, yio si gbéra rẹ̀ ga jù gbogbo ọlọrun lọ, yio si ma sọ̀rọ ohun iyanu si Ọlọrun awọn ọlọrun, yio si ma ṣe rere titi a o fi pari ibinu: nitori a o mu eyi ti a ti pinnu rẹ̀ ṣẹ.

37. Bẹ̃li on kì yio si kà Ọlọrun awọn baba rẹ̀ si, tabi ifẹ awọn obinrin, on kì yio si kà ọlọrun kan si: nitoriti yio gbé ara rẹ̀ ga jù ẹni gbogbo lọ.

38. Ṣugbọn ni ipò rẹ̀, yio ma bu ọlá fun ọlọrun awọn ilu olodi, ani ọlọrun kan ti awọn baba rẹ̀ kò mọ̀ ri ni yio ma fi wura, ati fadaka, ati okuta iyebiye, ati ohun daradara bu ọlá fun.

39. Bẹ̃ gẹgẹ ni yio ṣe ninu ilu olodi wọnni ti o lagbara julọ nipa iranlọwọ ọlọrun ajeji, ẹniti o jẹ́wọ rẹ̀ ni yio fi ogo fun, ti yio si mu ṣe alakoso ọ̀pọlọpọ, yio si pín ilẹ fun li ère.

40. Li akokò opin, ọba gusu yio kàn a, ọba ariwa yio si fi kẹkẹ́, ati ẹlẹṣin, ati ọ̀pọlọpọ ọkọ̀, kọ lu u bi afẹyika-ìji: on o si wọ̀ ilẹ wọnni yio si bò wọn mọlẹ, yio si rekọja.

41. Yio si wọ̀ ilẹ ologo nì pẹlu, ọ̀pọlọpọ li a o si bì ṣubu: ṣugbọn awọn wọnyi ni yio si bọ lọwọ rẹ̀, ani Edomu, ati Moabu, ati olori awọn ọmọ Ammoni.

Ka pipe ipin Dan 11