Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Amo 9:7-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ẹnyin kò ha dàbi awọn ọmọ Etiopia si mi, Ẹnyin ọmọ Israeli? li Oluwa wi. Emi kò ha ti mu Israeli goke ti ilẹ Egipti jade wá? ati awọn Filistini lati ilẹ Kaftori, ati awọn ara Siria lati Kiri.

8. Kiyesi i, Oluwa Ọlọrun mbẹ lara ilẹ ọba ti o kún fun ẹ̀ṣẹ, emi o si pa a run kuro lori ilẹ; ṣugbọn emi kì yio pa ile Jakobu run tan patapata, li Oluwa wi.

9. Wò o, nitori emi o paṣẹ, emi o si kù ile Israeli ninu awọn orilẹ-ède, bi ã ti kù ọkà ninu kọ̀nkọsọ, ṣugbọn woro kikini kì yio bọ́ sori ilẹ.

10. Gbogbo awọn ẹlẹṣẹ ninu enia mi yio ti ipa idà kú, ti nwipe, Ibi na kì yio le wa ba, bẹ̃ni kì yio ba wa lojijì.

11. Li ọjọ na li emi o gbe agọ Dafidi ti o ṣubu ró, emi o si dí ẹya rẹ̀; emi o si gbe ahoro rẹ̀ soke, emi o si kọ́ ọ bi ti ọjọ igbani:

12. Ki nwọn le ni iyokù Edomu ni iní, ati ti gbogbo awọn keferi, ti a pè nipa orukọ mi, li Oluwa ti o nṣe eyi wi.

Ka pipe ipin Amo 9