Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Titu 3:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Máa rán wọn létí kí wọn máa tẹríba fún ìjọba ati àwọn aláṣẹ, kí wọn máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, kí wọn sì múra láti máa ṣe iṣẹ́ rere gbogbo.

2. Kí wọn má sọ ìsọkúsọ sí ẹnikẹ́ni. Kí wọn kórìíra ìjà. Kí wọn ní ìfaradà. Kí wọ́n máa fi ìrẹ̀lẹ̀ bá gbogbo eniyan lò.

3. Nítorí nígbà kan rí, àwa náà ń ṣe wérewère, à ń ṣe àìgbọràn, ayé ń tàn wá jẹ, a jẹ́ ẹrú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, a sì ń jẹ ayé ìjẹkújẹ ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà. À ń hùwà ìkà ati ìlara. A jẹ́ ohun ìríra fún àwọn eniyan. Àwa náà sì kórìíra ọmọnikeji wa.

4. Ṣugbọn nígbà tí Ọlọrun fi inú rere ati ìfẹ́ rẹ̀ sí àwa eniyan hàn, ó gbà wá là;

5. kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rere kan tí a ṣe, ṣugbọn nítorí àánú rẹ̀ ni ó fi gbà wá là, nípa ìwẹ̀mọ́ pẹlu omi tí ó fi tún wa bí, ati Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fi sọ wá di ẹni titun.

6. Ó da Ẹ̀mí yìí lé wa lórí lọpọlọpọ láti ọwọ́ Jesu Kristi Olùgbàlà wa.

7. Ó dá wa láre nípa oore-ọ̀fẹ́ kan náà, tí a fi ní ìrètí láti di ajogún ìyè ainipẹkun.

8. Ọ̀rọ̀ tí ó dájú ni ọ̀rọ̀ yìí.Mo fẹ́ kí o tẹnumọ́ àwọn nǹkan wọnyi, kí àwọn tí ó ti gba Ọlọrun gbọ́ lè fi ọkàn sí i láti máa ṣe iṣẹ́ tí ó dára. Irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ dára, wọ́n sì ń ṣe eniyan ní anfaani.

9. Ṣugbọn yẹra fún iyàn jíjà lórí ọ̀rọ̀ wèrè ati ìtàn ìrandíran, ati ìjà, ati àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ òfin. Nítorí wọn kò ṣe eniyan ní anfaani, wọn kò sì wúlò rárá.

10. Bí o bá ti kìlọ̀ fún adíjàsílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tabi lẹẹmeji, tí kò gbọ́, yẹra fún un.

Ka pipe ipin Titu 3