Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Titu 2:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní tìrẹ, àwọn ohun tí ó bá ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro mu ni kí ó máa ti ẹnu rẹ jáde.

2. Àwọn àgbà ọkunrin níláti jẹ́ ẹni tí ó ń ṣe pẹ̀lẹ́, ẹni ọ̀wọ̀, ọlọ́gbọ́n, tí ó jinná ninu igbagbọ, ninu ìfẹ́ ati ninu ìfaradà.

3. Bákan náà, àwọn àgbà obinrin níláti jẹ́ ẹni tí gbogbo ìgbé-ayé wọn bá ti ìsìn Ọlọrun mu. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ onísọkúsọ tabi ẹrú ọtí. Wọ́n níláti máa kọ́ni ní ohun rere.

4. Kí wọn máa fi òye kọ́ àwọn ọdọmọbinrin wọn láti fẹ́ràn ọkọ wọn ati ọmọ wọn.

5. Kí wọn máa fara balẹ̀, kí wọn sì fara mọ́ ọkọ wọn nìkan. Kí wọn má ya ọ̀lẹ ninu iṣẹ́ ilé, kí wọn sì jẹ́ onínú rere. Kí wọn máa gbọ́ràn sí ọkọ wọn lẹ́nu, kí ẹnikẹ́ni má baà lè sọ ìsọkúsọ sí ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

6. Bákan náà, máa gba àwọn ọdọmọkunrin níyànjú láti fara balẹ̀.

7. Kí o ṣe ara rẹ ní àpẹẹrẹ rere ní gbogbo ọ̀nà. Ninu ẹ̀kọ́ tí ò ń kọ́ àwọn eniyan, kí wọn rí òtítọ́ ninu rẹ, kí wọn sì rí ìwà àgbà lọ́wọ́ rẹ.

8. Kí gbolohun ẹnu rẹ jẹ́ ti ọmọlúwàbí, tí ẹnìkan kò ní lè fi bá ọ wí. Èyí yóo mú ìtìjú bá ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe alátakò nígbà tí kò bá rí ohun burúkú kan sọ nípa wa.

Ka pipe ipin Titu 2