Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Kinni 6:3-12 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Bí ẹnìkan bá ń kọ́ àwọn eniyan ní ẹ̀kọ́ mìíràn, tí kò mọ ẹ̀kọ́ tí ó yè, ẹ̀kọ́ ti Oluwa wa Jesu Kristi, ati ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tí ó pé,

4. ìgbéraga ti sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ di aṣiwèrè, kò sì mọ nǹkankan. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ óo fẹ́ràn láti máa ṣe òfintótó ọ̀ràn, ati iyàn jíjà, àwọn ohun tí ó ń mú owú-jíjẹ, ìjà, ìsọkúsọ, ìfura burúkú,

5. ati àríyànjiyàn wá. Nǹkan wọnyi wọ́pọ̀ láàrin àwọn tí orí wọn ti kú, tí wọ́n ti yapa kúrò ní ọ̀nà òtítọ́. Wọ́n rò pé nítorí èrè ni eniyan fi ń ṣe ẹ̀sìn.

6. Òtítọ́ ni pé èrè ńlá wà ninu jíjẹ́ olùfọkànsìn, tí eniyan bá ní ìtẹ́lọ́rùn.

7. Nítorí a kò mú ohunkohun wá sinu ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè mú ohunkohun kúrò ninu rẹ̀.

8. Bí a bá ti ní oúnjẹ ati aṣọ, kí á ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu wọn.

9. Àwọn tí wọn ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa ṣubú sinu ìdánwò, tàkúté a sì mú wọn. Wọn a máa lépa ọpọlọpọ nǹkan tí kò mú ọgbọ́n wá ati àwọn nǹkan tí ó lè pa eniyan lára, irú nǹkan tí ó ti mú kí àwọn mìíràn jìn sinu ọ̀fìn ikú ati ìparun.

10. Ìfẹ́ owó ni ìpìlẹ̀ gbogbo nǹkan burúkú. Èyí ni àwọn mìíràn ń lépa tí wọ́n fi ṣìnà kúrò ninu igbagbọ, tí wọ́n sì fi ọwọ́ ara wọn fa ọpọlọpọ ìbànújẹ́ fún ara wọn.

11. Ṣugbọn ìwọ eniyan Ọlọrun, sá fún nǹkan wọnyi. Máa lépa òdodo, ati ìfọkànsìn Ọlọrun, igbagbọ, ìfẹ́, ìfaradà, ati ìwà pẹ̀lẹ́.

12. Máa ja ìjà rere ti igbagbọ. Di ìyè ainipẹkun mú. Ohun tí Ọlọrun pè ọ́ fún nìyí, òun sì ni ẹ̀rí rere tí o fi ẹnu ara rẹ jẹ́ níwájú ọpọlọpọ ẹlẹ́rìí.

Ka pipe ipin Timoti Kinni 6