Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Kinni 6:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ àjàgà ẹrú níláti rí i pé wọ́n ń bu ọlá fún àwọn ọ̀gá wọn ní ọ̀nà gbogbo, kí àwọn eniyan má baà sọ̀rọ̀ ìṣáátá sí orúkọ Ọlọrun ati ẹ̀kọ́ onigbagbọ.

2. Àwọn ẹrú tí wọ́n ní ọ̀gá onigbagbọ kò gbọdọ̀ sọ ara wọn di ẹgbẹ́ ọ̀gá wọn, wọn ìbáà jẹ́ ará ninu Kristi. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n níláti sìn wọ́n tara-tara, nítorí àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ fún jẹ́ arakunrin ninu igbagbọ ati ìfẹ́.Àwọn nǹkan wọnyi ni kí o máa fi kọ́ àwọn eniyan, kí o sì máa fi gbà wọ́n níyànjú.

3. Bí ẹnìkan bá ń kọ́ àwọn eniyan ní ẹ̀kọ́ mìíràn, tí kò mọ ẹ̀kọ́ tí ó yè, ẹ̀kọ́ ti Oluwa wa Jesu Kristi, ati ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tí ó pé,

4. ìgbéraga ti sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ di aṣiwèrè, kò sì mọ nǹkankan. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ óo fẹ́ràn láti máa ṣe òfintótó ọ̀ràn, ati iyàn jíjà, àwọn ohun tí ó ń mú owú-jíjẹ, ìjà, ìsọkúsọ, ìfura burúkú,

5. ati àríyànjiyàn wá. Nǹkan wọnyi wọ́pọ̀ láàrin àwọn tí orí wọn ti kú, tí wọ́n ti yapa kúrò ní ọ̀nà òtítọ́. Wọ́n rò pé nítorí èrè ni eniyan fi ń ṣe ẹ̀sìn.

6. Òtítọ́ ni pé èrè ńlá wà ninu jíjẹ́ olùfọkànsìn, tí eniyan bá ní ìtẹ́lọ́rùn.

7. Nítorí a kò mú ohunkohun wá sinu ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè mú ohunkohun kúrò ninu rẹ̀.

Ka pipe ipin Timoti Kinni 6