Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Kinni 5:14-25 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nítorí náà mo fẹ́ kí àwọn opó tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ tún lọ́kọ, kí wọ́n bímọ, kí wọ́n ní ilé tiwọn. Bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn kò ní fi ààyè sílẹ̀ fún ọ̀tá láti sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́.

15. Nítorí àwọn mìíràn ti yipada, wọ́n ti ń tẹ̀lé Satani.

16. Bí onigbagbọ obinrin kan bá ní àwọn opó ninu ẹbí rẹ̀, òun ni ó níláti ṣe ìtọ́jú wọn. Kò níláti di ẹrù wọn lé ìjọ Ọlọrun lórí, kí ìjọ lè mójútó àwọn tí wọ́n jẹ́ opó gidi.

17. Ó yẹ kí àwọn àgbà tí wọ́n bá ṣe iṣẹ́ aṣiwaju dáradára gba ìdálọ́lá ọ̀nà meji, pataki jùlọ àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ oníwàásù ati olùkọ́ni.

18. Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Má ṣe dí mààlúù tí ó ń tẹ ọkà lẹ́nu.” Ati pé, “Owó oṣù òṣìṣẹ́ tọ́ sí i.”

19. Bí ẹnìkan bá fi ẹ̀sùn kan àgbàlagbà, má ṣe kà á sí àfi tí ẹlẹ́rìí meji tabi mẹta bá wà.

20. Bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wí ní gbangba, kí ẹ̀rù lè ba àwọn yòókù.

21. Mo sọ fún ọ, níwájú Ọlọrun ati Kristi Jesu, ati àwọn angẹli tí Kristi ti yàn, pé kí o pa ọ̀rọ̀ yìí mọ́; má ṣe ojuṣaaju.

22. Má fi ìwàǹwára gbé ọwọ́ lé ẹnikẹ́ni lórí láti fi jẹ oyè ninu ìjọ, má sì di alábàápín ninu ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíràn. Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ mọ́.

23. Má máa mu omi nìkan, ṣugbọn máa lo waini díẹ̀, nítorí inú tí ń yọ ọ́ lẹ́nu ati nítorí àìsàn tí ó máa ń ṣe ọ́ nígbà gbogbo.

24. Àwọn kan wà tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn hàn sí gbogbo eniyan, àwọn adájọ́ ti mọ̀ wọ́n kí wọ́n tó mú wọn dé kọ́ọ̀tù. Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn a máa pẹ́ kí ó tó hàn sóde.

25. Bákan náà ni, iṣẹ́ rere a máa hàn sí gbogbo eniyan. Bí wọn kò bá tilẹ̀ tíì hàn, wọn kò ṣe é bò mọ́lẹ̀ títí.

Ka pipe ipin Timoti Kinni 5