Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Kinni 3:8-16 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Bákan náà ni kí àwọn diakoni jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́. Kí wọn má ṣe jẹ́ ẹlẹ́nu meji. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó ń mutí para. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ oníwọ̀ra eniyan.

9. Wọ́n níláti di ohun ìjìnlẹ̀ igbagbọ mú pẹlu ẹ̀rí-ọkàn tí ó mọ́.

10. A sì níláti kọ́kọ́ dán wọn wò ná; bí wọ́n bá jẹ́ aláìlẹ́gàn, kí á wá fi wọ́n sí ipò diakoni.

11. Bákan náà ni àwọn obinrin níláti jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́; kí wọn má jẹ́ abanijẹ́. Kí wọn jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, kí wọn jẹ́ ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ninu ohun gbogbo.

12. Diakoni kò gbọdọ̀ ní ju aya kan lọ; ó sì gbọdọ̀ káwọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dáradára ati gbogbo ìdílé rẹ̀.

13. Nítorí àwọn tí wọn bá ṣe iṣẹ́ diakoni dáradára ti ṣí ọ̀nà ipò gíga fún ara wọn. Wọ́n lè sọ̀rọ̀ pẹlu ọpọlọpọ ìgboyà nípa igbagbọ tí ó wà ninu Kristi Jesu.

14. Mo ní ìrètí láti wá sọ́dọ̀ rẹ láìpẹ́, ṣugbọn mò ń kọ ìwé yìí,

15. nítorí bí mo bá pẹ́ kí n tó wá, kí o lè mọ̀ bí ó ti yẹ láti darí ètò ilé Ọlọrun, èyí tíí ṣe ìjọ Ọlọrun alààyè, òpó ati ààbò òtítọ́.

16. Kò sí ẹni tí kò mọ̀ pé àṣírí ẹ̀sìn wa jinlẹ̀ pupọ:Ẹni tí ó farahàn ninu ẹran-ara,tí a dá láre ninu ẹ̀mí,tí àwọn angẹli fi ojú rí,tí à ń waasu rẹ̀ láàrin àwọn alaigbagbọ,tí a gbàgbọ́ ninu ayé,tí a gbé lọ sinu ògo.

Ka pipe ipin Timoti Kinni 3