Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Kinni 2:10-15 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ṣugbọn kí ọ̀ṣọ́ wọn jẹ́ ọpọlọpọ iṣẹ́ rere, bí ó ti yẹ fún àwọn obinrin olùfọkànsìn.

11. Obinrin níláti máa fi ìfarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ pẹlu ìtẹríba.

12. N kò gbà fún obinrin láti jẹ́ olùkọ́ni tabi láti ní àṣẹ lórí ọkunrin. Kí obinrin máa panumọ́ ni.

13. Nítorí Adamu ni a kọ́kọ́ dá, kí á tó dá Efa.

14. Kì í sì í ṣe Adamu ni a tàn jẹ, obinrin ni a tàn jẹ tí ó fi di ẹlẹ́ṣẹ̀.

15. Ṣugbọn a óo gba obinrin là nípa ọmọ-bíbí, bí àwọn obinrin bá dúró láì yẹsẹ̀ ninu igbagbọ ati ìfẹ́ ati ìwà mímọ́ pẹlu ìwà ìkóra-ẹni-níjàánu.

Ka pipe ipin Timoti Kinni 2