Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Keji 3:5-11 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ní òde, ara wọn dàbí olùfọkànsìn, ṣugbọn wọn kò mọ agbára ẹ̀sìn tòótọ́. Ìwọ jìnnà sí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀.

6. Ara wọn ni àwọn tíí máa tọ ojúlé kiri, tí wọn máa ń ki àwọn aṣiwèrè obinrin mọ́lẹ̀, àwọn obinrin tí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ti wọ̀ lẹ́wù, tí wọn ń ṣe oríṣìíríṣìí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.

7. Àwọn obinrin wọnyi ń kẹ́kọ̀ọ́ nígbà gbogbo, sibẹ wọn kò lè ní ìmọ̀ òtítọ́.

8. Bí Janesi ati Jamberesi ti tako Mose, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkunrin wọnyi tako òtítọ́. Orí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ ti kú, a sì ti ṣá wọn tì ní ti igbagbọ.

9. Ṣugbọn wọn kò lè máa bá irú ìwà bẹ́ẹ̀ lọ pẹ́ títí. Nítorí pé ìwà wèrè wọn yóo hàn kedere sí gbogbo eniyan, gẹ́gẹ́ bí ti Janesi ati Jamberesi ti hàn.

10. Ṣugbọn ìwọ ní tìrẹ, o ti tẹ̀lé ẹ̀kọ́ mi, ati ọ̀nà ìgbé-ayé mi, ète mi, ati igbagbọ mi, sùúrù mi, ìfẹ́ mi ati ìfaradà mi,

11. ninu inúnibíni, ninu irú ìyà tí ó bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu, ní Listira, ati oríṣìíríṣìí inúnibíni tí mo faradà. Oluwa ni ó yọ mí ninu gbogbo wọn.

Ka pipe ipin Timoti Keji 3