Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Keji 2:12-26 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Bí a bá faradà á,a óo bá a jọba.Bí a bá sẹ́ ẹ,òun náà yóo sẹ́ wa.

13. Bí àwa kò bá tilẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé,òun ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nígbà gbogbo,nítorí òun kò lè tan ara rẹ̀ jẹ.”

14. Máa rán àwọn eniyan létí nípa nǹkan wọnyi. Kìlọ̀ fún wọn níwájú Ọlọrun pé kí wọn má máa jiyàn lórí oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ tí kò wúlò, tíí sìí máa da àwọn tí ó bá gbọ́ lọ́kàn rú.

15. Sa gbogbo ipá rẹ láti ṣe ara rẹ ní ẹni tí ó yege níwájú Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí kò ṣe ohun ìtìjú pamọ́, tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ.

16. Yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ asán ati ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ, nítorí àwọn tí wọ́n fẹ́ràn irú ọ̀rọ̀ wọnyi túbọ̀ ń jìnnà sí ẹ̀sìn Ọlọrun ni.

17. Ọ̀rọ̀ wọn dàbí egbò-rírùn tí ó ń kẹ̀ siwaju. Irú wọn ni Himeneu ati Filetu,

18. àwọn tí wọ́n ti ṣìnà kúrò ninu òtítọ́, tí wọn ń sọ pé ajinde tiwa ti ṣẹlẹ̀, tí wọn ń mú kí igbagbọ ẹlòmíràn yẹ̀.

19. Ṣugbọn Ọlọrun ti fi ìpìlẹ̀ yìí lélẹ̀, tí ó dúró gbọningbọnin. Àkọlé tí a kọ sára èdìdì tí ó wà lára rẹ̀ nìyí: “Ọlọrun mọ àwọn ẹni tirẹ̀,” ati pé, “Gbogbo àwọn tí ó bá ń pe orúkọ Oluwa níláti kúrò ninu ibi.”

20. Kì í ṣe àwọn ohun èèlò wúrà ati ti fadaka nìkan ni ó ń wà ninu ilé ńlá. Àwọn nǹkan tí wọ́n fi igi ati amọ̀ ṣe wà níbẹ̀ pẹlu. À ń lo àwọn kan fún nǹkan pataki; à ń lo àwọn mìíràn fún ohun tí kò ṣe pataki tóbẹ́ẹ̀.

21. Bí ẹnikẹ́ni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò ninu àwọn nǹkan wọnyi, olúwarẹ̀ yóo di ohun èèlò tí ó níye lórí, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó wúlò fún baálé ilé. Yóo di ẹni tí ó ṣetán láti ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ rere.

22. Yẹra fún àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọ̀dọ́. Máa lépa òdodo ati ìṣòtítọ́, ìfẹ́, ati alaafia, pẹlu àwọn tí ó ń képe Oluwa pẹlu ọkàn mímọ́.

23. Má bá wọn lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ati ọ̀rọ̀ òpè. Ranti pé ìjà ni wọ́n ń dá sílẹ̀.

24. Iranṣẹ Oluwa kò sì gbọdọ̀ jà. Ṣugbọn ó níláti máa ṣe jẹ́jẹ́ sí gbogbo eniyan, kí ó jẹ́ olùkọ́ni rere, tí ó ní ìfaradà.

25. Kí ó fi ìfarabalẹ̀ bá àwọn tí ó bá lòdì sí i wí, bóyá Ọlọrun lè fún wọn ní ọkàn ìrònúpìwàdà, kí wọ́n lè ní ìmọ̀ òtítọ́,

26. kí wọ́n lè bọ́ kúrò ninu tàkúté Satani, tí ó ti fi mú wọn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin Timoti Keji 2