Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Keji 2:1-16 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nítorí náà, ìwọ ọmọ mi, jẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ tí ó wà ninu ìdàpọ̀ pẹlu Kristi Jesu sọ ọ́ di alágbára.

2. Àwọn ohun tí o gbọ́ láti ẹnu mi níwájú ọpọlọpọ ẹlẹ́rìí, ni kí o fi lé àwọn olóòótọ́ eniyan lọ́wọ́, àwọn tí ó tó láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.

3. Farada ìpín tìrẹ ninu ìṣòro gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ogun Kristi Jesu.

4. Kò sí ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ tí ó gbọdọ̀ tún tojú bọ àwọn nǹkan ayé yòókù. Àníyàn rẹ̀ kanṣoṣo ni láti tẹ́ ọ̀gágun rẹ̀ lọ́rùn.

5. Kò sí ẹni tí ó bá ń súré ìje tí ó lè gba èrè àfi bí ó bá pa òfin iré ìje mọ́.

6. Àgbẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ lóko ni ó kọ́ ní ẹ̀tọ́ sí ìkórè oko.

7. Gba ohun tí mò ń sọ rò. Oluwa yóo jẹ́ kí ìtumọ̀ rẹ̀ yé ọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

8. Ranti Jesu Kristi tí a jí dìde kúrò ninu òkú, tí a bí ninu ìdílé Dafidi. Ìyìn rere tí mò ń waasu nìyí.

9. Ninu iṣẹ́ yìí ni mo ti ń jìyà títí mo fi di ẹlẹ́wọ̀n bí ọ̀daràn. Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè fi ẹ̀wọ̀n de ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

10. Nítorí náà, mo farada ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́, kí àwọn náà lè rí ìgbàlà tí ó wà ninu Kristi Jesu pẹlu ògo tí ó wà títí lae.

11. Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí, pé,“Bí a bá bá a kú,a óo wà láàyè pẹlu rẹ̀.

12. Bí a bá faradà á,a óo bá a jọba.Bí a bá sẹ́ ẹ,òun náà yóo sẹ́ wa.

13. Bí àwa kò bá tilẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé,òun ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nígbà gbogbo,nítorí òun kò lè tan ara rẹ̀ jẹ.”

14. Máa rán àwọn eniyan létí nípa nǹkan wọnyi. Kìlọ̀ fún wọn níwájú Ọlọrun pé kí wọn má máa jiyàn lórí oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ tí kò wúlò, tíí sìí máa da àwọn tí ó bá gbọ́ lọ́kàn rú.

15. Sa gbogbo ipá rẹ láti ṣe ara rẹ ní ẹni tí ó yege níwájú Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí kò ṣe ohun ìtìjú pamọ́, tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ.

16. Yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ asán ati ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ, nítorí àwọn tí wọ́n fẹ́ràn irú ọ̀rọ̀ wọnyi túbọ̀ ń jìnnà sí ẹ̀sìn Ọlọrun ni.

Ka pipe ipin Timoti Keji 2