Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Keji 1:8-17 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Nítorí náà má ṣe tijú láti jẹ́rìí fún Oluwa wa tabi fún èmi tí mo wà lẹ́wọ̀n nítorí rẹ̀. Ṣugbọn gba ìjìyà tìrẹ ninu iṣẹ́ ìyìn rere pẹlu agbára Ọlọrun,

9. tí ó gbà wá là, tí ó pè wá láti ya ìgbé-ayé wa sọ́tọ̀. Kì í ṣe pé ìwà wa ni ó dára tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi pè wá. Ṣugbọn ó pè wá gẹ́gẹ́ bí ètò tí òun fúnrarẹ̀ ti ṣe, ati nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí ó fi fún wa nípasẹ̀ Kristi Jesu láti ayérayé.

10. Ètò yìí ni ó wá hàn kedere nisinsinyii nípa ìfarahàn olùgbàlà wa Kristi Jesu, tí ó gba agbára lọ́wọ́ ikú, tí ó mú ìyè ati àìkú wá sinu ìmọ́lẹ̀ nípa ìyìn rere.

11. Ọlọrun yàn mí láti jẹ́ akéde ati aposteli ati olùkọ́ni.

12. Ìdí nìyí tí mo fi ń jìyà báyìí. Ṣugbọn ojú kò tì mí. Nítorí mo mọ ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé. Ó sì dá mi lójú pé ó lè pa ìṣúra tí mo fi pamọ́ sí i lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ ńlá náà.

13. Di àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ tí ó yẹ, tí o ti gbà láti ọ̀dọ̀ mi mú, pẹlu igbagbọ ati ìfẹ́ tí ó wà ninu Kristi Jesu.

14. Pa ìṣúra rere náà mọ́ pẹlu agbára Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ń gbé inú rẹ.

15. O kò ní ṣàìmọ̀ pé gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè Esia ti sá kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ó fi mọ́ Fugẹlọsi ati Hemogenesi.

16. Kí Oluwa ṣàánú ìdílé Onesiforosi. Kò ní iye ìgbà tí ó ti tù mí ninu, ninu ìṣòro mi. Kò tijú pé ẹlẹ́wọ̀n ni mí.

17. Nígbà tí ó dé Romu, ó fi ìtara wá mi kàn, ó sì rí mi.

Ka pipe ipin Timoti Keji 1