Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Tẹsalonika Kinni 5:7-17 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Nítorí òru ni àwọn tí ń sùn ń sùn, òru sì ni àwọn tí ó ń mutí ń mutí.

8. Ṣugbọn ní tiwa, ojúmọmọ ni iṣẹ́ tiwa, nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á farabalẹ̀, kí á wọ aṣọ ìgbàyà igbagbọ ati ìfẹ́, kí á dé fìlà ìrètí ìgbàlà.

9. Nítorí Ọlọrun kò pè wá sinu ibinu, ṣugbọn sí inú ìgbàlà nípasẹ̀ Oluwa wa Jesu Kristi,

10. tí ó kú nítorí tiwa, ni ó pè wá sí, pé bí à ń ṣọ́nà ni, tabi a sùn ni, kí á jọ wà láàyè pẹlu rẹ̀.

11. Nítorí náà, ẹ máa tu ara yín ninu, kí ẹ sì máa fún ara yín ní ìwúrí, bí ẹ ti ń ṣe.

12. Ẹ̀yin ará, à ń bẹ̀ yín pé kí ẹ máa bu ọlá fún àwọn tí ń ṣe làálàá láàrin yín, tí wọn ń darí yín nípa ti Oluwa, tí wọn ń gbà yín níyànjú.

13. Ẹ máa fi ìfẹ́ yẹ́ wọn sí gidigidi nítorí iṣẹ́ wọn. Ẹ máa wà ní alaafia láàrin ara yín.

14. Ará, à ń rọ̀ yín pé kí ẹ máa gba àwọn tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́ níyànjú; bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn tí ó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn; ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́; ẹ máa mú sùúrù pẹlu gbogbo eniyan.

15. Kí ẹ rí i pé ẹnikẹ́ni kò fi burúkú gbẹ̀san burúkú lára ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn nígbà gbogbo kí ẹ máa lépa nǹkan rere láàrin ara yín ati láàrin gbogbo eniyan.

16. Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo.

17. Ẹ máa gbadura láì sinmi.

Ka pipe ipin Tẹsalonika Kinni 5