Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Tẹsalonika Kinni 2:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ará, ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé wíwá tí a wá sọ́dọ̀ yín kì í ṣe lásán.

2. Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀, lẹ́yìn tí a ti jìyà, tí a ti rí ẹ̀gbin ní Filipi, ni a fi ìgboyà nípa Ọlọrun wá tí a sọ̀rọ̀ ìyìn rere Ọlọrun fun yín láàrin ọpọlọpọ àtakò.

3. Nítorí pé ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í ṣe ohun ìṣìnà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ohun èérí tabi ti ìtànjẹ.

4. Ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti kà wá yẹ, tí ó fi iṣẹ́ ìyìn rere lé wa lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni à ń sọ̀rọ̀, kì í ṣe láti tẹ́ eniyan lọ́rùn, bíkòṣe pé láti tẹ́ Ọlọrun tí ó mọ ọkàn wa lọ́rùn.

5. Nítorí, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀, a kò wá pọ́n ẹnikẹ́ni, a kò sì wá ṣe àṣehàn bí ẹni tí ìwọ̀ra wà lọ́kàn rẹ̀. A fi Ọlọrun ṣe ẹlẹ́rìí!

6. Bẹ́ẹ̀ ni a kò wá ìyìn eniyan, ìbáà ṣe láti ọ̀dọ̀ yín, tabi láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn;

7. bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a wà ní ipò láti gba ìyìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Kristi. Ṣugbọn à ń ṣe jẹ́jẹ́ láàrin yín, àní gẹ́gẹ́ bí obinrin alágbàtọ́ tíí ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ tí ó ń tọ́jú.

8. Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn wa fà sọ́dọ̀ yín; kì í ṣe ìyìn rere nìkan ni a fẹ́ fun yín, ṣugbọn ó dàbí ẹni pé kí á gbé gbogbo ara wa fun yín, nítorí ẹ ṣọ̀wọ́n fún wa.

9. Ará, ẹ ranti ìṣòro ati làálàá wa, pé tọ̀sán-tòru ni à ń ṣiṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà ara wa, kí á má baà ni ẹnikẹ́ni ninu yín lára nígbà tí à ń waasu ìyìn rere Ọlọrun fun yín.

10. Ẹ̀yin gan-an lè jẹ́rìí, Ọlọrun náà sì tó ẹlẹ́rìí wa pé, pẹlu ìwà mímọ́ ati òdodo ati àìlẹ́gàn ni a fi wà láàrin ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́;

11. gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ pé bí baba ti rí sí àwọn ọmọ rẹ̀ ni a rí sí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín;

12. tí à ń gbà yín níyànjú, tí à ń rọ̀ yín, tí à ń kìlọ̀ fun yín nípa bí ó ti yẹ kí ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín bí ẹni tí Ọlọrun pè sinu ìjọba ati ògo rẹ̀.

13. Nítorí náà, àwa náà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo, nítorí nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ẹ gbọ́ lẹ́nu wa, ẹ gbà á bí ó ti rí gan-an ni. Bí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ẹ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ eniyan. Ọ̀rọ̀ náà sì ń ṣiṣẹ́ ninu ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́.

Ka pipe ipin Tẹsalonika Kinni 2