Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Tẹsalonika Kinni 1:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Èmi Paulu, ati Silifanu, ati Timoti, ni à ń kọ ìwé yìí sí ìjọ Tẹsalonika, tíí ṣe ìjọ Ọlọrun Baba ati ti Jesu Kristi Oluwa.Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia máa wà pẹlu yín.

2. À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo nítorí gbogbo yín, a sì ń ranti yín ninu adura wa nígbà gbogbo.

3. Ninu adura wa sí Ọlọrun Baba wa, à ń ranti bí igbagbọ yín ti ń mú kí ẹ ṣiṣẹ́, tí ìfẹ́ yín ń jẹ́ kí ẹ ṣe akitiyan, tí ìrètí tí ẹ ní ninu Oluwa wa Jesu Kristi sì ń mú kí ẹ ní ìfaradà.

4. Ẹ̀yin ará, àyànfẹ́ Ọlọrun, a mọ̀ pé Ọlọrun ni ó yàn yín.

5. Nígbà tí a mú ìyìn rere wá sí ọ̀dọ̀ yín, a kò mú un wá pẹlu ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan; ṣugbọn pẹlu agbára ninu Ẹ̀mí Mímọ́ ni, ati pẹlu ọpọlọpọ ẹ̀rí tí ó dáni lójú. Ẹ̀yin náà kúkú ti mọ irú ẹni tí a jẹ́ nítorí tiyín nígbà tí a wà láàrin yín.

Ka pipe ipin Tẹsalonika Kinni 1