Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 9:13-21 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Jakọbu ni mo yàn, Esau ni mo kọ̀.”

14. Kí ni kí á wá wí sí èyí? Kí á wí pé Ọlọrun ń ṣe àìdára ni bí? Rárá o!

15. Nítorí ó sọ fún Mose pé, “Ẹni tí mo bá fẹ́ ṣàánú ni n óo ṣàánú; ẹni tí mo bá sì fẹ́ yọ́nú sí ni n óo yọ́nú sí.”

16. Nítorí náà, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí eniyan ti fẹ́ tabi bí ó ti gbìyànjú tó ni Ọlọrun fi ń yàn án, bí ó bá ti wu Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ ni.

17. Nítorí Ọlọrun sọ ninu Ìwé Mímọ́ nípa Farao pé, “Ìdí tí mo fi fi ọ́ jọba ni pé, mo fẹ́ fi ọ́ ṣe àpẹẹrẹ bí agbára mi ti tó, ati pé kì ìròyìn orúkọ mi lè tàn ká gbogbo ayé.”

18. Nítorí náà, ẹni tí ó bá wu Ọlọrun láti ṣàánú, a ṣàánú rẹ̀, ẹni tí ó bá sì wù ú láti dí lọ́kàn, a dí i lọ́kàn.

19. Wàyí, ẹnìkan lè sọ fún mi pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló dé tí Ọlọrun fi ń bá eniyan wí? Ta ni ó tó takò ó pé kí ó má ṣe ohun tí ó bá wù ú?”

20. Ṣugbọn ta ni ọ́, ìwọ ọmọ-eniyan, tí o fi ń gbó Ọlọrun lẹ́nu? Ǹjẹ́ ìkòkò lè wí fún ẹni tí ó ń mọ ọ́n pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe mí báyìí?”

21. Àbí amọ̀kòkò kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣe amọ̀ rẹ̀ bí ó ti wù ú bí? Bí ó bá fẹ́, ó lè fi amọ̀ rẹ̀ mọ ìkòkò tí ó wà fún èèlò ọ̀ṣọ́. Bí ó bá sì tún fẹ́, ó lè mú lára amọ̀ kan náà kí ó fi mọ ìkòkò mìíràn fún èèlò lásán.

Ka pipe ipin Romu 9