Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 9:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Òtítọ́ ni ohun tí mò ń sọ yìí; n kò purọ́, nítorí Kristi ni ó ni mí. Ọkàn mi tí Ẹ̀mí ń darí sì jẹ́ mi lẹ́rìí pẹlu, pé,

2. ohun ìbànújẹ́ ńlá ati ẹ̀dùn ọkàn ni ọ̀ràn àwọn eniyan mi jẹ́ fún mi nígbà gbogbo.

3. Mo fẹ́rẹ̀ lè gbadura pé kí á sọ èmi fúnra mi di ẹni ègún, kí á yà mí nípa kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí ti àwọn ará mi, àwọn tí a jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà.

4. Ọmọ Israẹli ni wọ́n. Àwọn ni Ọlọrun yàn bí ọmọ rẹ̀. Àwọn ni ó fi ògo rẹ̀ hàn fún. Àwọn náà ni ó bá dá majẹmu, tí ó fún ní Òfin rẹ̀, tí ó sì kọ́ lọ́nà ẹ̀sìn rẹ̀. Àwọn ni ó ṣe ìlérí fún.

5. Àwọn ni irú-ọmọ àwọn baba-ńlá ayé àtijọ́. Láàrin wọn ni Mesaya sì ti wá sáyé gẹ́gẹ́ bí eniyan. Ìyìn ni fún Ọlọrun, ẹni tíí ṣe olùdarí ohun gbogbo, lae ati laelae. Amin.

6. Sibẹ, kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti kùnà patapata. Nítorí kì í ṣe gbogbo àwọn tí a bí sinu ìdílé Israẹli ni ọmọ Israẹli tòótọ́.

Ka pipe ipin Romu 9